Iroyin Ayọ F’awọn Ti Wọn Nifẹsi Bọọlu Gbigba Bii Ẹgbẹ Agbabọọlu Barcelona Ṣe Tọwọ Bọ Iwe Adehun Lati Da Ile-ẹkọ Bọọlu Silẹ Ni Ipinlẹ Bayelsa

Ẹgbẹ Agbabọọlu to gbayi l’agbaye nni, Barcelona FC ni wọn ti tọwọ bọ iwe adehun lati da ile-iwe ẹkọ bọọlu gbigba kalẹ s’ipinlẹ Bayelsa.

Ẹni to jẹ Kọmiṣọna fun Ere idaraya ni ipinlẹ naa, Dokita Daniel Igali lo buwọlu iwe adehun naa fun ipinlẹ Bayelsa nigba ti Ọgbẹni Villa Garris buwọlu iwe fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona nibi aṣekagba idije ere bọọlu alafẹsẹgba kan ti wọn fi sọri Gomina ni Yenagoa.

Idije naa lo jẹ ti t’ọkunrin ati obinrin. Nibi aṣekagba naa ni ẹgbẹ agbabọọlu l’ọkunrin Okoroma United to n ṣ’oju ijọba ibilẹ ati ẹgbẹ agbabọọlu l’obinrin Active Ladies of Agudama ti jawe olubori. Awọn Okoroma ni wọn lọ ile pẹlu Ogoji miliọnu naira (₦40 million) nigba ti awọn Active Ladies gba miliọnu mẹwa naira (₦10 million).

Gomina ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri lo fi idunnu rẹ han pe adehun tuntun yii yoo ṣina ayọ f’awọn ọdọ ti yoo si jẹ koriya fun wọn lati kopa ninu ere idaraya ki wọn le dẹkun iwa ibajẹ.

O tẹsiwaju pe iṣejọba oun yoo tubọ maa k’owo le ẹka ere idaraya bẹẹ lo n ṣe ileri pe iṣẹ akanṣe papa iṣere to le gba eeyan ẹgbẹrun lọna ọgbọn yoo jẹ pipari l’ọdun 2027.

Diri ni, lojuna ati mu idagbasoke ba awọn ọdọ ni awọn ṣe gbe ere idaraya naa kalẹ to si n gbooro si lojoojumo. O wa gboriyin fawọn agbabọọlu naa pe wọn ṣe daadaa. Gomina tun ki awọn igbimọ idije ọhun ati awọn ti wọn ṣe onigbọwọ fun wọn.

Lara awọn ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni Aarẹ tẹlẹri fun Ajọ to n risi bọọlu alafẹsẹgba lorilẹede Naijira, Amaju Pinnick ati Akọwe ajọ naa, Mohammed Sanusi.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search