Awọn alatilẹyin Igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijira, Atiku Abubakar ti fi ikilọ ranṣẹ si awọn ẹgbẹ alatako gbogbo pe ko si ẹnikẹni ni ẹkun Guusu to le koju Aarẹ Bola Tinubu nitori naa ki wọn ma fi tikẹti aarẹ wọn jin fun guusu bi bẹẹ kọ wọn fẹ ki atunwọle Tinubu rọrun niyẹn.
Ninu ọrọ kan ti wọn fi lede fawọn akọroyin nilu Abuja ni agbenusọ fun Atiku lori ọrọ iroyin, Olusola Sanni jiyan pe ẹgbẹ oṣelu APC ti fi eeyan silẹ lati guusu fun atunwọle nitori naa ko le jẹ oun to mu ọgbọn wa nilana oṣelu lati fa eeyan kalẹ lati ẹkun kan naa.
O tẹnpẹlẹ mọ pe oṣelu ni ṣe pẹlu ọgbọn inu, eto to peye ati iṣiro lai fi ti itara ṣe. Olusola tẹsiwaju pe ko si idi kankan lati fi tikẹti jin fun guusu nitori ti eeyan lati guusu ba wọle a jẹ pe ẹkun guusu yoo ti lo ju ẹkun ariwa lọ ni iṣejọba to ba maa fi di ọdun 2027.
Awọn alatilẹyin Atiku ni abosi lasan ni ọpọ awọn tọrọ kan lagbo oṣelu n ṣe paapaa julọ awọn ti wọn ṣatilẹyin fun aarẹ ana, Goodluck Jonathan ni ọdun 2011. Wọn fikun pe lootọ awọn mọ pe o wa lọkan awọn ara guusu ila-oorun lati jẹ aarẹ ṣugbọn ki wọn ma sọ oṣelu di oun ti a n naa bi ọja.
Lakotan, igun naa wa rọ awọn ẹgbẹ alatako lati jẹ ki awọn f’imọ ṣọkan lati fa ẹni to to koju ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lai fi ti itara ṣe.