Ina Ọba: Ẹwọn Ọdun Marundinlaadọrin (75) Ni Ile Ẹjọ Da Fun Minisita Tẹlẹ Ri

Alakoso abi minisita tẹlẹ ri fun ọrọ ohun amusagbara ni orilẹ-ede Naijiria, Mamman Saleh ni ile-ẹjọ giga apapọ kan to wa ni ilu Abuja ti da ni ẹwọn ọdun marundinlaaadọrin (75 years) fun jijẹ ẹbi ẹsun ṣiṣe owo kan, biliọnu mẹtalelọgbọn (₦33b) mọkuku nipasẹ iwa jegudujera.

Onidajọ James Ọmọtọṣọ lo da’jọ ẹbi fun Mamman l’ori awọn ẹsun oniga mejila (12 count charges) ti ajọ EFCC pe tako-o.

Fun ẹsun mẹwaa ninu mejila, ile-ẹjọ da lẹjọ ewọn ọdun mẹwaa fun ọkọọkan, ati idajọ ẹwọn ọdun mẹta ati meji fun ẹbi ẹsun marun-un ati mẹrin miiran, ṣugbọn ti yoo lo saa awọn ẹsun naa papọ.

Idajọ naa ni Onidajọ Ọmọtọṣọ gbe si ori pepele pe, awọn olupẹjọ fidi ẹsun wọn mu’lẹ ṣugbọn ti olulẹjọ si kuna lati ro arojare lori awọn ẹsun naa.

Ile-ẹjọ fi idi rẹ mulẹ pe Mamman jẹ’bi sisan $665,700 ni owo kishi (cash) lai gbe gba ile ifowopamọ kankan lati fi ra dukia si ilu Abuja. Siwaju si, o tun jẹbi ẹsun didari owo to yẹ fun ibudo ohun amuṣagbara to wa ni ilu Mambilla ati ilu Zungeru fun ipese ina-ọba ni orilẹ-ede Naijiria gba ibomiran ti ko ba ofin mu.

Ni ipari adajọ naa bu ẹnu atẹ lu Mamman pe dipo ko lo ipo rẹ tẹlẹ gẹgẹ bii minisita fun ọrọ ina-ọba ati ẹka ohun amuṣagbara lapapọ lati fi wa ojutuu si iṣoro idakureku ina-ọba, n ṣe ni o n fi owo ilu ṣe ararindin lai bikita nipa igbesiaye ara ilu rara.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search