Olukọni tẹlẹri fun ikọ agba ọjẹ orilẹede Naijiria (Super Eagles), Sunday Oliseh ti sọ pe kikọ lati san owo to t’owo ati ipese nibi iṣẹ ti ko munadoko lo n ṣokun fa ti ọpọ awọn agbabọọlu ninu idije liigi agba ọjẹ orilẹede Naijiria (NPFL) fi n lọ gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu l’oke okun.
Oliseh ni ṣiṣe itọju awọn agbabọọlu ṣe pataki lati ri pe awọn ti wọn n ṣe daadaa ninu liigi ilẹ wa o maa salọ silu oyinbo.
Oliseh ṣalaye pe okowo ni bọọlu gbigba jẹ atipe nidi rẹ ni ọpọ awọn agbabọọlu ti n ṣe jijẹ mimu ati itọju awọn ẹbi bẹẹ ni wọn o maa fi nkan pamọ fun ọjọ-ọla.
O ni bo ṣe ẹgbẹrun kan owo dọla ($1000) ni wọn n fun wọn, owo to jọju ni bi wọn ba paarọ rẹ si naira.
Oliseh fi igba ti o ṣi n gba bọọlu ṣakawe pe wọn o ki n jẹ awọn l’owo bẹẹ ni wọn kii da owo awọn duro biotilẹjẹpe owo naa ko to nkan ṣugbọn ọpọ awọn agbabọọlu ṣe ẹtọ ninu ẹbi pẹlu rẹ ti wọn si ri owo tujọ.
O fikun pe ki wọn ma da ẹnikẹni lẹbi ti wọn ba kuro ninu liigi ilẹ wa nitori awọn naa ni ẹbi ti wọn fẹ tọju ati pe ki wọn maa fi ara wọn si ipo awọn agbabọọlu naa ki wọn le ri bo ṣe n ri lara.
Ni ipari ọrọ rẹ, Oliseh ni bi wọn ba fẹ ki awọn agbabọọlu duro nilẹ yii, wọn gbọdọ ṣe atunṣe ligi naa ki koriya le wa fun awọn agbabọọlu. O wa rọ ajọ to n ri si liigi agba ọjẹ orilẹede Naijiria naa (NPFL) lati ṣe itọju awọn agbabọọlu daadaa.