Gomina tẹlẹri nipinlẹ Kano, Rabiu Musa Kwankwanso ti ṣaṣọ loju bi ọmọ rẹ obinrin ṣe gba niyanju ni ọdun 2023 lati ṣatilẹyin fun Peter Obi to jẹ adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ Oṣelu Labour Party nigba naa.
Kwankwanso sọ eyi di mimọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan to ti n sọrọ nipa ayipada to ti de ba iwa awọn ọdọ lori oṣelu lorilẹede Naijira.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọpọ awọn ọdọ o fi ọkan si ẹya tabi ẹsin mọ nitori ohun to jẹ wọn l’ogun julọ ni adari gidi ati iṣejọba ti yoo mu oriire wa fun mutumuwa.
O tẹsiwaju pe nkan ti awọn ọdọ nifẹsi ta ba n sọrọ nipa oṣelu o yatọ gedengbe si ohun ti awọn tiṣaaju nifẹsi. O fi kun wipe ọpọ awọn adari ni oye agbara ti awọn ọdọ ati ẹrọ ayelujara ni lori ipo ti oṣelu n lọ lorilẹede Naijira.
Kwankwanso tun ṣafikun pe awọn ọdọ ti wọn fe dibo n beere fun iṣejọba to dantọ lati koju gbogbo aiṣedeede to wa lorilẹede yii yatọ si igbẹkẹle ẹsin ati ẹya lati ṣe iruju.
Kwankwanso ni oun ati Obi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NDC laipẹ yii lati ẹgbẹ oṣelu ADC latari aigbọra ẹni ye laarin ẹgbẹ naa.