Mo Lero Pe Opin Ti De Ba Irin-ajo Mi Nidi Iṣẹ Tiata Ni Bi Ọdun Mẹta Sẹyin – Linda Ejiofor

Gbajugbaja oṣerebinrin to gb’ẹyẹ nibi ayẹyẹ AMVCA, Linda Ejiofor ti ṣalaye bi o ṣe ba ipenija pade nidi iṣẹ rẹ to bẹẹ de bi pe oun lero pe oun ni idaduro ko ti di pe ayipada rere de t’oun fi di ẹni to n gba ami ẹyẹ meji lẹẹkan ṣoṣo.

O sọrọ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti ọkọ rẹ to tun jẹ oṣerekunrin naa, Ibrahim Suleiman nibẹ lo ti sọ pe ṣiṣiye meji lo mu oun bẹrẹ sii bẹ Ọlọhun to si fun oun ni awọn itan gidi meji to mu iranwọ wa.

O tẹsiwaju pe Ọkọ oun ṣaduroti gidi l’asiko naa bi o tilẹ jẹ pe oun tiraka lati ni igbagbọ ninu iṣẹ t’oun n ṣe. O wa dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba ati Ọkọ rẹ fun aduroti nigba ti nkan di fun oun.

Linda lo laluyọ nibi ami ẹyẹ AMVCA ti ọdun yii nibi to ti gba meji lẹẹkan ṣoṣo to jẹ alakọkọ iru rẹ latigba ti wọn ti da ami ẹyẹ naa kalẹ.

Linda Ejiofor bẹrẹ iṣẹ tiata ni ọdun 2008 pẹlu ere agbelewo ọlọsẹẹsẹ Tinsel ko to bẹrẹ sinima ni san-an. O gba ami ẹyẹ AMVCA alakọkọ ni ọdun 2015.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search