Idunnu Ṣubu Layọ L’agboole Oduduwa Bi Ọọni Ile-Ifẹ Ati Olori Mariam Ajibola Ṣe Ki Awọn Ejire Ọmọbakunrin Kaabo S’aafin

Ọọni ti Ile-ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyeye Ogunwusi y’ayọ awọn ibeji ọmọbakunrin tuntun jojolo ti Ọlọrun fi ta oun ati Olori Mariam Ogunwusi l’ọrẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ninu ọrọ kan ti Ori Ade naa fi lede lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ lo ti dupẹ fun Ọlọrun pe ayọ ati alaafia ni iya ati awọn ọmọ naa wa.

Kabiesi ki Ọlọrun fun iṣẹ iyanu rẹ ti ko l’opin ati ibukun rẹ to pọ jaburata. O wa ki gbogbo agboole Oduduwa ku oriire paapaa julọ Olori Mariam Ajibola Ogunwusi fun ayọ ti awọn ejirẹ ọmọbakunrin to ṣẹṣẹ wọ agboole naa wa.

Ti ẹ o ba gbagbe ni ọdun 2022 ni Ọọni fẹ awọn Olori mẹfa laarin oṣu mẹta lẹyin ti igbeyawo wọn pẹlu Olori Naomi f’ori ṣọnpọn. Awọn Olori naa ni Olori Mariam Anako, Olori Elizabeth Akinmudai, Olori Tobiloba Philips, Olori Ashley Adegoke, Olori Ronke Ademiluyi, ati Olori Temitope Adesegun.

Awọn Ejirẹ yii ni wọn jẹ ikeji yoo wọ aafin Ọjaja lẹyin ti Olori Tobiloba naa bi ibeji ni ọdun 2024.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search