Ajọ Amnesty International Ke Gbajare Lori Awọn Ọmọ Ile-ẹkọ Ti Wọn Jigbe Nipinlẹ Borno Ati Oyo Bi Ọga Agba Ile-iṣẹ Ọlọpa Ṣe Ṣe Abẹwo Si Ijọba Ibilẹ Oriire Nipinlẹ Oyo

Ajọ ajafẹtọ ọmọ-niyan Amnesty International ti ke gbajare lori ogunlọgọ awọn ọmọ ile-iwe ti wọn jigbe l’ẹkun ariwa ati guusu ti wọn si n rawọ ẹbẹ si awọn tọrọ kan lati gbe igbesẹ ni kiakia lati doola ẹmi awọn ọmọ naa ki wọn si mojuto aabo to peye lori awọn ile-iwe kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ kan ti wọn fi lede loni ajọ naa ṣapejuwe awọn iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii nkan ti o ṣe maa gbọ s’eti nitori awọn ikọlu naa daju le awọn ile-ẹkọ, akẹkọ ati agbegbe laarin ọjọ perete.

Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ o kere tan awọn ọmọ ile-iwe mejilelọgọrin ni wọn jigbe laarin ọjọ kẹtala si ọjọ kẹẹdogun oṣu yii ninu awọn ikọlu ọtọọtọ nipinlẹ Borno ati Oyo.

Amnesty International ṣalaye pe awọn akẹkọ mejilelogoji ni wọn jigbe l’ọjọ kẹtala ati ikẹrinla nigba ti awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ṣe ikọlu si awọn ile-iwe ni awọn ijọba ibilẹ Askira Uba ati Chibok nipinlẹ Borno. Ẹwẹ ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ awọn akẹkọ ogoji mii ni wọn tun jigbe lasiko ikọlu awọn agbesunmọmi.

Awọn ile-iwe ti ọrọ naa kan ni ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ati Government Day Junior Secondary School (GDSS) Mussa, Local Authority School ni ijọba ibilẹ Askira Uba nipinlẹ Borno, Ahoro-Esinele ati Community Grammar School ni agbegbe Ahoro-Esinele ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.

Ajọ naa tọka si pe imi ninu awọn ọmọ naa o ju ọmọ ọdun meji lọ leyi to n ṣafihan bi ikọlu si awọn ile-iwe ṣe n le si lojoojumọ bẹẹ ni wọn tun ke si awọn tọrọ kan lati ṣe iwadi ọrikiniwin ki awọn ọdaran naa f’imu kata ofin nitori ọpọ igba awọn ti wọn ba fara kaaṣa ninu ikọlu o ki n gba idajọ to peye.

Amnesty International tẹsiwaju pe aipese aabo to peye fun awọn araalu tako ofin ilẹ wa.

Ẹwẹ, ọga agba ile-iṣẹ ọlọpa ilẹ wa Olatunji Rilwan Disu ti ṣe abẹwo si ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ. O fi aidunnu rẹ han lori iṣẹlẹ naa bẹẹ lo ba awọn ẹbi tọrọ kan kẹdun. O wa fi ọkan awọn araalu balẹ pe ile-iṣẹ ọlọpa maa sa gbogbo ipa lati ri pe awọn ọmọ naa pada sile ti idajọ ododo yoo si waye lori awọn ẹlẹkẹru naa.

Ijinigbe l’awọn ile-ẹkọ jẹ ọkan gboogi lara awọn ipenija aabo to n koju orilẹede Naijiria ti ọpọ awọn eeyan si n ke si ijọba lati jẹ ki aabo munadoko l’awọn ile-ẹkọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search