Ile-ẹjọ Agba To Wa L’Abuja Gba Beeli El-Rufai Pẹlu Awọn Ilana To Le

Ile-ẹjọ giga nilu Abuja ti gba beeli gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai ni ọgọrun miliọnu lori ẹsun pe o jẹbi igbesẹ lati jẹ ki eto aabo dẹnu kọlẹ.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori beeli rẹ adajọ agba Joyce Abdulmalik paṣẹ awọn ọna abayọ to le dọindọin lori beeli naa.

Ile-ẹjọ naa paṣẹ pe El Rufai gbọdọ ni oniduro to jẹ oṣiṣẹ ijọba ni ipele kẹtadinlogun to si gbọdọ fi iwe lati ile ifowopamọ to ṣafihan owo oṣu fun o kere tan oṣu mẹta ti ọga ile ifowopamọ naa buwọlu lu. O ṣafikun pe oniduro naa gbọdọ ni ile ni agbegbe Asokoro tabi Maitama to si gbọdọ fi iwe ile naa silẹ fun ile-ẹjọ.

Lara awọn ọna abayọ fun beeli naa ni pe El Rufai gbọdọ ko gbogbo awọn iwe irina rẹ kalẹ fun ile-ẹjọ bẹẹ ni o gbọdọ maa dari si ile-iṣẹ giga ajọ DSS ni aago mẹwa ni gbogbo ọjọ jimoh to ba kẹyin ninu oṣu titi ti ile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ.

Bẹẹ ni ile-ẹjọ tun ni ki El Rufai mu iwe iduro wa lati ọwọ alaga ipejọpọ awọn lọba lọba nilu Kaduna. Adajọ wa kii nilọ pe ti ko ba tẹle awọn ilana yii ile-ẹjọ maa da pada sinu akolo awọn DSS.

El Rufai lo ti wa l’akolo awọn DSS lati oṣu keji ọdun yii lori awọn ọrọ to sọ nibi ifọrọwanilẹnuwo to ti jẹwọ pe oun ati awọn kan tẹti si awọn ipe oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ aabo Nuhu Ribadu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search