Gbajugbaja arẹwa oṣerebinrin, Bukky Wright lo t’ẹnu bọ itan ti ọpọ awọn eniyan to fi mọ awọn ololufẹ rẹ ko gbọ ri nipa rẹ. Alaye rẹ kan ohun to sun de idi iṣẹ tiata, igbesi-aye rẹ ni ibẹrẹ pẹpẹ, abuda eniyan to jẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nibi eto apero kan to waye ti wọn pe ni “Scar2Shine Panel” ni oṣerebinrin naa ti tu awọn aṣiri nla naa nipa ara rẹ. Bukky Wright, Lekan Wasiudeen ati Mercy Aigbe lo joko ni ipo alejo afiwepe nibi eto naa.
Ogunna gbongbo oṣere naa ṣalaye ohun to gbe wọ idi iṣẹ tiata. O ni idile bọrọkinni ni oun ti gbe l’ọkọ ni ibẹrẹ aye rẹ ṣugbọn ti wọn fi ọwọ ọla gba ọmọ l’ọwọ oun, l’eyi to fa bi oun ṣe darapọ mọ iṣẹ tiata nitori ki awọn ọmọ oun le ri ibi wa oun si l’ọjọ iwaju, oun ko l’ero pe okiki oun le bu ja’de bayii gẹgẹ bii oṣere t’oun ti pe wọn ro oun pin lati ja mọ nnkan kan nile ọkọ aarọ rẹ.
Ninu ohun to tun wi ni pe oun jẹ onitiju ẹda ti ko ni apẹpẹ pupọ, l’eyi to fa ti oun kii ṣe e yọ’ju si ọpọ ode ariya, ti Mercy Aigbe naa si da apara pe gẹlẹ bẹẹ ni oun naa ri.
Siwaju si, Bukky jẹ ko ye pe idagbasoke oun ko rọrun, lara ilakọja rẹ ni asiko ewe ni iriri ile olorogun ati bi ko ṣe tete mọ baba rẹ.
Ko tan si’bẹ, oṣerebinrin naa lo anfaani naa lati tan imọlẹ si aṣigbọ kan nipa rẹ pe, yatọ fun oun ti ọpọ gbagbọ pe ọmọ ilu Ile-Ife ni oun ṣe, o jẹ ko di mimọ pe ọmọ Ẹgba ni’lu Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun ni ohun ṣe.