Aarẹ Bola Tinubu yan Ọjọgbọn Aina Gẹgẹ Bii Oludari Ajọ JAMB Tuntun

Aarẹ Bola Tinubu ti yan Ọjọgbọn Ṣẹgun Aina gẹgẹ bii Oludari tuntun fun ajọ to n risi igbaniwọle silẹ ẹkọ giga nilẹ wa (JAMB) lati gbaṣẹ lọwọ Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti saa rẹ yoo pari l’ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu keje ọdun yii.

Iyansipo yii lo fi lede ninu ọrọ kan ti oludamọran pataki si aarẹ lori iroyin ati ọgbọn inu, Bayọ Ọnanuga buwọlu.

Gẹgẹ bii ọrọ naa ṣe sọ Ọjọgbọn Aina k’ẹkọ imọ ẹrọ kọnputa nile ẹkọ giga fasiti ti Obafemi Awolowo n’ile-ife to si n’imọ nipa ohun amayedẹrun igbalode, ẹrọ iṣedanwo n’ilana igbalode ati atunṣe awọn ile-iwe.

Aina ti yoo pe ọmọ ogoji ọdun ni ọdun yii lo ti ni iriri to le l’ọdun mẹẹdọgbọn nidi iṣẹ ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ kaakiri lori atunṣe igbalode.

Ọrọ naa ṣapejuwe Aina gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọjọgbọn to kere ju l’ọjọ ori lorilẹede Naijira ti yoo si jẹ ẹni to kere ju ninu gbogbo awọn oludari ti ajọ JAMB ti ni.

Ile-iṣẹ aarẹ sọ pe ko to di pe wọn yan si po, o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii oludamọran si awọn ajọ onidanwo bii NECO ati NABTEB bẹẹ lo tun jẹ ara awọn ajọ to niṣe pẹlu imọ ẹrọ lorilẹede Naijira.

Aarẹ Tinubu wa sọ pe oun nigbagbọ pe oludari tuntun yii yoo ṣiṣẹ lori awọn akanṣe iṣẹ ti Oloyede ti ṣe kalẹ tẹlẹ pẹlu iriri ati ọgbọn to ni.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search