Aṣiri Tu! Iyawo Akin Ọlaiya Ṣ'alaye Ohun Tu Igbeyawo Wọn Ka
Iyawo ti gbajugbaja oṣere tiata nni, Akin Olaiya fẹ laipẹ yii, Nafisat lo ti jade wa fi ẹsun kan pe ni ṣe lo maa n lu oun to si n f’idi rẹ mulẹ pe lootọ ni ipinya ti waye laarin awọn.
O sọ eyi ninu fọnran kan to fi lede lori ayelujara loni. Ni ọjọ aje ni atẹjade kan han de lori ayelujara nipa ipinya awọn mejeeji.
Ninu atẹjade to ni ọpọ ariyanjiyan yii ni oṣerekunrin naa ti ni Nafisat kọ ko ẹru kuro ninu ile lai ṣe pe oun mọ si, to si jẹ pe gbogbo igbiyanju oun lati pe ko pada wa, pabo lo ja si.
Nigba to n fesi si ohun ti Akin Olaiya sọ yii, Nafisat ni oun kuro ninu igbeyawo naa lẹyin oṣu diẹ nitori lilu ati aiṣe itọju to peye f’oun.
O tẹsiwaju pe lati ọdun to koja l’awọn o ti si papọ mọ. Gẹgẹ bo ṣe wi, ọpọ awọn eeyan ni wọn ro pe oun fi igbeyawo oun silẹ lai si idi, to si n ṣalaye pe ko si obinrin to maa fi ile alayọ silẹ ti ko ba nidi.
O ni oun fẹ Akin nitori ifẹ pẹlu pe ọpọlọpọ ọdun lo wa laarin awọn, t’oun si lero pe ifẹ awọn a dalẹ ṣugbọn nkan pada bajẹ.
Nafisat ni bi o ti lẹ jẹ pe oun o le jade lati maa sọ ohun to ṣẹlẹ ninu igbeyawo oun sita ṣugbọn ọpọ nkan lo ṣokunfa b’oun ṣe fi ile-ọkọ silẹ.
O fi aidunnu rẹ han pe ọkọ oun tẹlẹ pada lọ fẹ ọrẹ oun timọ-timọ leyi to ni o n ṣafihan ara awọn nkan to ṣẹlẹ ninu igbeyawo naa.
O fikun pe nitori bi wọn ṣe tọ oun, ko ṣeeṣe f’oun lati jade sọ gbogbo nkan to ṣẹlẹ laarin awọn amọ oun ti fi gbogbo rẹ le Ọlọhun l’ọwọ.
Ti ẹ o ba gbagbe inu oṣu keje ọdun to kọja l’awọn mejeeji ṣe igbeyawo eyi to daru lẹyin oṣu marun. Eleyi ni igbeyawo keji ti oṣerekunrin naa maa ṣe lẹyin ti igbeyawo alakọkọ rẹ f’ori ṣọnpọn lori ẹsun lilu ati yiyan ale.