Awọn Ọdọ Ọ Ṣetan Lati Koju Awọn Jẹgudujẹra Oloṣelu Ati Eto Aabo To Mẹhe – Gehgeh

Sọrọ sọrọ ori ẹrọ ayelujara Emmanuel Oboruste ti gbogbo eeyan mọ si Gehgeh lo ti bẹnu atẹ lu ifesi awọn ọdọ ati awọn ẹṣọ alaabo lorilẹede yii si awọn ọrọ to niṣe pẹlu aabo ati iṣejọba nilẹ yii.

Eleyi lo sọ ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ rẹ. Ninu ọrọ naa ni Gehgeh ti ṣe afiwe nkan to n ṣẹlẹ lorilẹede South Africa ati ohun to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijira to si n sọ pe o jọ pe iṣọkan wa ninu iṣe awọn ọmọ orilẹede South Africa.

O ni k’awọn ọmọ orilẹede Naijiria wo bi awọn ọmọ orilẹede South Africa ṣe f’imọ ṣọkan lati ṣe akanṣe iṣẹ kan ti awọn ijọba ati ẹṣọ alaabo si kun wọn lọwọ.

O tẹsiwaju pe ṣugbọn lorilẹede Naijira awọn ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti ati awọn obinrin ti wọn ṣiṣẹ idana laladani ni awọn ọlọpa n le kiri bẹẹ l’awọn ọdọ gan o ṣetan lati dide gba ijọba lọwọ awọn jẹgudujẹra oloṣelu.

Ọrọ Gehgeh yii tẹlẹ awọn iṣẹlẹ ikọlu kaakiri orilẹede Naijiria leyi to n mu ibẹrubojo ba awọn araalu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search