Aṣiri Tu! Igboho L’oun Mọ Awọn Ti Wọn Wa Nidi Ijinigbe L’Ọyọ

Gbajumọ ajijangbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti leri pe oun ma fi orukọ awọn oloṣelu ti wọn wa nidi ijinigbe awọn ọmọ ile-iwe ati akẹkọọ nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.

O sọ eyi nigba to n ba awọn adari tuntun fun ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijira ti Akinteye Babatunde lewaju wọn sọrọ n’ile rẹ to wa l’agbegbe Soka Ni’badan.

Ninu fọnran kan to n tanka ori ẹrọ ayelujara bayii ni Igboho ti sọ pe oun ti yọnda ara oun lati lọ k’oju awọn agbesunmọmi naa ṣugbọn ti ijọba ipinlẹ Ọyọ kọ jalẹ.

O tẹsiwaju pe oun o beere owo kankan lọwọ iṣejọba Seyi Makinde lati lọ doola awọn mẹtadinlaadọta ti wọn wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.

Igboho ni ti wọn ba fun oun laye lati lọ ka wọn mọ, gbogbo wọn maa f’ẹsẹ fẹ nitori eeyan ni wọn, o si ṣeeṣe lati tu wọn ka.

O fikun pe oun mọ awọn oloṣelu ti wọn jẹ baba isalẹ fun wọn ti wọn si n fun wọn ni owo ati ohun ija loriṣiriṣi. O wa leri pe gbogbo wọn l’oun maa darukọ ni kọọkan ti wọn o ba jawọ iṣẹ laabi wọn.

Ajijangbara naa tẹsiwaju pe ohun ti wọn ṣe l’asiko Jonathan naa ni wọn n ṣe fun Tinubu nitori wọn fẹ tu ilu ka mọọ lori ni ki wọn le le awọn alatilẹyin jina si i. O ni ka gba pe kii ṣe eremọde ni ijinigbe to ṣẹlẹ lo yii.

O ni lẹyin ti wọn ko awọn ọmọ lọ nipinlẹ Ọyọ t’oun si gba lati lọ k’oju wọn ni ijọba ni rara nitori awọn ọdaran agbesunmọmi naa ni awọn maa pa awọn ọmọ naa ti o ba fi tipatipa wọ igbo lọ.

Igboho ni to ba jẹ lootọ ni wọn ni l’ọkan lati doola awọn ọmọ naa ki wọn gba oun ati awọn ikọ oun laye lati le wọn kuro ninu igbo ẹkun iwọ-oorun guusu nitori o da oun l’oju pe wọn o le duro lẹgbẹ oun ati awọn ọmọ oun pẹlu gbogbo ohun ija ti wọn ni.

O fikun pe lẹyin t’oun gba aṣẹ lọwọ ijọba apapọ fun ikọ ogun Iru Ẹkun lati koju awọn agbesunmọmi ni ijọba ipinlẹ Ọyọ kilọ pe k’oun ma gbe igbesẹ kankan ko ma baa fa iku awọn ọmọ naa. O ni pẹlu bi ijọba aarẹ ana, oloogbe Muhammadu Buhari ṣe buru to, o pari saa rẹ ki lo wa de ti wọn fi n di Tinubu to jẹ ọmọ Yoruba lọwọ. O ni Tinubu lo da oun pada silu nitori naa oun o le ta koo ati pe ki lo de ti wọn ṣe fẹ ba iṣejọba rẹ jẹ gan?

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ tẹlẹri ati adije dupo aarẹ l’ẹgbẹ oṣelu ADC Atiku Abubakar, Paul Ibe lo ti rọ ajọ ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ n’ilẹ yii (DSS) lati pe Sunday Igboho ko le tọka si awọn oloṣelu ti wọn wa nidi ijinigbe nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.

Ibe sọ eyi ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ nibi to ti ni ti Igboho ba mọ nipa awọn ajinigbe naa ki awọn ẹṣọ alaabo pe ko le ṣe iranwọ lati doola awọn ọmọ naa.

O ni o ṣe pataki lati sa gbogbo ipa ki wọn le doola awọn ọmọ naa ati awọn olukọ.

Bẹẹ lo bẹnu atẹ lu bi ijọba Aarẹ Tinubu ṣe n fesi si ijinigbe awọn ọmọ ile-iwe to ṣẹlẹ ni agbegbe Mussa nipinlẹ Borno l’oṣu to kọja.

O wa fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn dakẹ lori awọn ọmọ ti wọn jigbe ni Borno bẹẹ lo n beere pe nigba wo ni wọn maa fun awọn naa ni iru akiyesi ti wọn n fun awọn ti wọn jigbe nijọba ibilẹ Oriire.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹẹdogun oṣu karun-un ni awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ṣe ikọlu si awọn ile-iwe mẹta ọtọọtọ nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ ti wọn si ko awọn olukọ ati akẹkọọ ti wọn le ni ogoji bẹẹ ni wọn ṣe ikọlu si awọn ile-iwe mẹta mii l’agbegbe Mussa nipinlẹ Borno ti wọn si ko awọn ọmọ ti wọn le ni aadọta.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search