Ile-iṣẹ Ọlọpa Ẹka Ipinlẹ Ọyọ Doola Ẹnikan Ti Wọn Jigbe Bi Awọn Amuludun Loriṣiriṣi Ṣe N Pe Fun Atunṣe Si Eto Aabo To Mẹhe

Ile-iṣẹ ọlọpa ẹka tipinlẹ Ọyọ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọlọdẹ ati awọn ẹṣọ alaabo mii ni wọn ti f’ọwọ ofin mu awọn afurasi ajinigbe mẹta ti wọn si doola ẹnikan ti wọn jigbe l’agbegbe Otu l’Oke Ogun n’ipinlẹ Ọyọ.

Wọn sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede eyi ti agbẹnusọ DSP Ayanlade Olayinka buwọlu. Ninu atẹjade naa ni ile-iṣẹ ọlọpa ti ṣalaye pe awọn gba ipe ijaya lat’ọdọ awọn ọlọdẹ ti awọn agbesunmọmi kọlu nigba ti wọn n d’ẹgbẹ lọ.

Awọn ọlọpa ni ko s’ẹni to f’arapa nigba ti awọn ọlọdẹ kọkọ ko firi awọn ọdaran naa ṣugbọn bi wọn ṣe pe awọn ọlọpa lati wa kun wọn lọwọ ni awọn ẹlẹkẹru naa da ibọn bolẹ.

Nibẹ ni wọn ti doola ọgbẹni Mosudi Gbolagade ẹni aadọta ọdun ti wọn jigbe ni agbegbe Okaka. Lara awọn ohun ti wọn ri nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ní awọn ibọn oriṣiriṣi ati ada.

Kọmisọna Ọlọpa wa gboṣuba kare fun awọn ọlọdẹ naa ati awọn ẹṣọ alaabo ti wọn ṣiṣẹ naa.

Eyi lo tẹle ikọlu to waye di awọn ile-iwe mẹta l’agbegbe Esiele, Yamota ati Alawusa l’ọjọ kẹẹdogun oṣu yii ti wọn ti ji awọn ọmọ ile-iwe to le l’ogoji ati awọn olukọ 

Ẹwẹ, awọn amuludun loriṣiriṣi ni wọn ti da si ọrọ eto aabo to mẹhe ati bi nkan o ṣe lọ deede lorilẹde Naijiria.

Gbajugbaja oṣerekunrin Kunle Remi ati olorin Olumide Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si ID Cabasa ni wọn ti fi aidunnu wọn han pẹlu awọn ọrọ ti wọn fi lede lori itakun ibanidọrẹ wọn.

Kunle Remi lo n ṣapejuwe bo ṣe nira fun-un lati sun nitori ironu bi nkan ṣe n lọ lorilẹede Naijira paapaa julọ awọn ọmọ ile-iwe ti wọn ṣi wa ni igbekun. O tẹsiwaju pe pẹlu bi nkan o ṣe lọ deede yii ko si ẹnikẹni to dẹkun igbaradi idibo ọdun 2027. O wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati ma jẹ ki ọkan wọn le si gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nitori o ṣeeṣe ki wọn maa wuwa ko kan mi ti wọn ba jẹ k’ọkan wọn yi.

Ni tiẹ, ID Cabasa bẹnu atẹ lu eto aabo to mẹhe ati bi o ṣe jọ pe o ti fẹẹ ma di baraku fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria. Ninu fọnran kan to fi lede lo ti ni awọn ọpọlọpọ ikọlu to ti n ṣẹlẹ lorilẹede Naijira ti n fa ki awọn araalu ma bikita mọ paapaa julọ nigba ti wọn ti fi da ẹsin ati ẹya. O wa pe fun ijọba lati gbe igbesẹ akin lati dẹkun ikọlu ojoojumọ yii.

Awọn mejeeji yii naa ti wa kun awọn gbajugbaja amuludun ti wọn ti pe fun atunṣe si eto aabo orilẹede Naijiria ko le tubọ le dọindọin.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search