Ni bii ayajọ awọn ewe iyẹn (Children’s Day) to ma n wa’ye l’ọdọdun t’ọdun 2026 ṣe ko l’anaa ode yii to tun ja si ọjọ ọdun Ileya awọn musulumi, ọpọlọpọ awọn amuludun bi oṣere, olorin ati awọn awọn gbajumọ ajafẹtọ lo n f’ara ya, ti awọn miiran si n sunkun gbangba lati pe ijọba si akiyesi l’ori ọrọ awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn olukọ ni ile-ẹkọ Girama ati alakọbẹrẹ ti awọn afurasi agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, ni agbegbe Ogbomoṣọ ni ipinlẹ Ọyọ, ti wọn ṣi wa ni igbekun awọn olubi ẹda to ji wọn gbe, ninu eyi ti awọn ọmọ wẹwẹ lati ọdun meji, mẹta pọ ninu wọn.
Igba akọkọ kọ ni eyi ti awọn gbajumọ ati ilumọọka l’aarin ilu yoo kigbe l’ori ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe eyi ni pato. Wọn ti bẹrẹ si ni s’ọrọ lati igba to ti waye ṣugbọn ti t’anaa yii peleke ni bo ṣe jẹ ayajọ awọn ọmọde.
Ọpọ wọn lo di ẹbi ru ijọba pe wọn kuna lati daabobo awọn eniyan l’aarin ilu, ti wọn si tun kuna lati doola awọn ti wọn ji gbe l’asiko ninu eyi ti wọn ti fi ọbẹ rẹ ọkunrin olukọ kan l’ọrun pa l’aarin wọn.
Ninu awọn to ja’de ni Fọlarin Falana to jẹ gbajumọ olorin; ajafẹtọ, ati ọmọ gbajugbaja amofin-ajafẹtọ, Fẹmi Falana, o ni nnkan ti buru gan l’ori eto aabo wa ati pe kosi idunnu kankan ninu ajọdun awọn ọmọde t’ọdun yii nitori l’ara awọn ọmọ to yẹ ka ma dunnu wa ni ahamọ awọn ẹhana ajinigbe.
Olorin miiran, Jaywon naa tun ja’de s’ọrọ pada pe bi Aarẹ Tinubu ba mọ pe oun ko kato l’ori ọrọ aabo ilẹ yii, ko tete sọ lati wa ojutuu.
Awọn gbajugbaja oṣerebinrin meji, Bambam ati Kiekie ninu fọnran ọtọtọ ti wọn ṣe pẹlu omije l’oju fi ẹkun kikoro beere pe kinni ohun to kan ati pe ṣe ijinigbe ti wa kuro ni ohun kayefi ni to ti wa di ohun ailakasi?
Elomiran, ti oun naa s’ọrọ ni gbajugbaja ajafẹtọ ati minisita tẹlẹ fun ọrọ eto ẹkọ ni Naijiria, Oby Ezekwesili, o pe ijọba Naijiria ti ja awọn ọmọ wẹwẹ wa kulẹ gba l’ori idaabobo wọn.
Ninu ọrọ ọtọtọ wọn l’ayọjọ awọn ọmọ wẹwẹ, Gomina Makinde ati Aarẹ Tinubu jẹ ko di mimọ pe awọn ko gbagbe awọn ọmọ naa, bẹẹ ni awọn ko kawọ gbera l’ori ọrọ eto aabo koda t’ọsan t’oru l’awọn fi n ṣe igbiyanju lati doola wọn ki alaafia o si j’ọba.