Ẹgbẹ awọn olukọ (NUT) ni orilẹ-ede Naijiria ti paṣẹ fun awọn olukọ ni ile-ẹkọ Girama ati alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Ọyọ, bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu kẹfa lati gun le iyanṣẹlodi l’ori ọrọ ijinigbe to waye lati ọwọ awọn ajinigbe-agbesunmọmi si awọn olukọ ati akẹẹkọ ni awọn ile-ẹkọ kan ni ijọba ibilẹ Oriire ni agbegbe Ogbomoṣọ ni ipinlẹ Ọyọ.
Aṣẹ naa lo jade ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ (NUT), Comrade Audu Titus Amba ati Akọwe Apapọ ẹgbẹ, Dọkita Clinton J. Ikpitibo buwọlu pe ki awọn olukọ ni ipinlẹ Ọyọ o ta kete si iṣẹ bẹrẹ lati oni ọjọ kinni, ki awọn olukọ lawọn ipinlẹ to ku o jade ni ọjọ keji oṣu kẹfa fun iwọde ifẹhonuhan lori ọrọ awọn akẹẹkọ ati olukọ ti awọn ajinigbe-agbesunmọmi mu ni igbekun.
Lai bikita nipa ọrọ iyanju Gomina Makinde pe ki iyanselodi o ma waye ati idasi Aarẹ Tinubu pe ki wọn o gba awọn aṣọgbo ẹgbẹrun kan fun aabo inu igbo ni ipinlẹ Ọyọ.
Lai bikita nipa ọrọ iyanju Gomina Makinde pe ki iyanselodi o ma waye ati idasi Aarẹ Tinubu pe ki wọn o gba awọn aṣọgbo ẹgbẹrun kan fun aabo inu igbo ni ipinlẹ Ọyọ.
Ẹgbẹ naa ṣalaye pe igbesẹ wọn lo ṣe pataki latari bi ọpọ irawọ ẹbẹ si awọn eleto aabo ṣe ti ja si pabo lai si ojutuu si ọrọ naa.
Ẹwẹ, iṣẹlẹ ijinigbe ni ijọba ibilẹ Oriire yii lo ti bi ọpọ ikọbi-ara-si lati ọdọ ara ilu ati ijọba ninu eyi ti Gomina Ṣeyi Makinde ati awọn ikọ rẹ ṣe abẹwo si agbegbe naa ni opin ọsẹ yii, bakanna ni ikọ alagbara ti Aarẹ Bọla Tinubu fi ranṣẹ lati ilu Abuja ninu eyi ti ati fi Oludamọran Pataki lori Eto Aabo, Nuhu Ribadu; alakoso fun eto aabo, Christopher Musa; Ọga Agba Ọlọpa, Kayọde Ẹgbẹtokun; Ajirọba si Aarẹ, Fẹmi Gbajabiamila ati Oloye Sunday Dare to jẹ ọkan ninu awọn agbẹnusọ fun aarẹ to tun jẹ ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ naa ti yọju si ilu naa lopin ọsẹ to kọja.