Adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC, Atiku Abubakar ti ni ki Aarẹ Tinubu dẹkun ati maa di ẹbi eto aabo to mẹhe lorilẹde Naijiria ru ẹgbẹ oṣelu PDP.
Atiku ni ọwọ ẹgbẹ oṣelu APC labẹ ijọba aarẹ ana oloogbe Muhammadu Buhari ni Tinubu ti j’ogun eto aabo to mẹhe.
Ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ lorilẹede yii lo gba ẹnu agbẹnusọ rẹ, Paul Ibe sọrọ nigba to n fesi si ọrọ ti oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ aabo Nuhu Ribadu sọ nipa ijinigbe awọn ọmọ ile-iwe ati olukọ nipinlẹ Ọyọ.
Awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ni wọn ṣe ikọlu si ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ ti wọn si ji awọn olukọ ati akẹkọọ to le ni ogoji ni awọn ile-ẹkọ mẹta ọtọọtọ l’ọjọ kẹẹdogun oṣu to kọja.
Ni igbiyanju kiakia lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Tinubu ran awọn jankanjankan ninu ijoba rẹ bii olori awọn oṣiṣẹ Femi Gbajabiamila, Nuhu Ribadu ati awọn mii lọ si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.
Nigba ti Ribadu n sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ti ni ajogun ba ni eto aabo to mẹhe fun Tinubu to si n d’ẹbi ru ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu esi rẹ, Ibe ni kii ṣe nkan to ṣe gbọ s’eti pe oludamọran si aarẹ n di ẹbi aile gba awọn ọmọ ati olukọ ti wọn jigbe n’ipinlẹ Ọyọ silẹ le ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn ti gbe ijọba silẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lati ọdun mọkanla sẹyin.
Ibe bẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ṣe lo odidi ọsẹ meji ki wọn to lọ ṣe abẹwo ẹnlẹ nbẹun si awọn ẹbi awọn ti wọn jigbe.
O ni ọwọ ẹni ti Tinubu ti gba ijọba ni o ti j’ogun eto aabo to mẹhe. O fikun pe ki wọn dẹkun ati maa d’ẹbi ru gbogbo eeyan yatọ si ijọba wọn nikan nigba ti awọn ọmọ ọlọmọ n runpa l’akolo awọn ajinigbe ni ipinlẹ Ọyọ, Borno ati awọn ibo mii.
Ọpọ awọn ẹgbẹ alatako bii Peter Obi, Omoyele Sowore ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti sọrọ lori eto aabo to mẹhe lorilẹde Naijiria ti wọn si n pe fun ijọba to wa l’ode lati tete wa nkan ṣe sii.