Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti da ile olojule mẹta to wa l’agbegbe Lako l’ọna Aiyegun–Anaye nilu Ibadan eyi to niṣe pẹlu iṣẹlẹ ijinigbe ti iwadi n lọ lori rẹ lọwọ bayi wo.
Didawo yii lo wa lati ọwọ awọn oṣiṣẹ ile-iṣẹ ijoba to n ṣamojuto iṣẹ-ilu ati igbokegbodo ọkọ l’oni ti awọn ọlọpa si tẹlẹ wọn lẹyin.
Gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe sọ, ile yii ni iwadi fi han pe nibẹ ni wọn ji aburo minisita fun ohun amuṣagbara tẹlẹri Adebayo Adelabu, Iyaafin Olaide Busayo Adegoke John-Paul ati awọn ibeji rẹ Peter ati Paul.
Awọn mẹtẹẹta yii ni iroyin gbe pe wọn jigbe ni Elewura l’agbegbe Challenge nilu Ibadan l’ọjọ kẹta oṣu yii.
Ijọba ni igbesẹ lati da ile naa wo wa lara awọn ilakaka wọn lati ri’wọ ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mii bo’lẹ nipinlẹ Ọyọ.
Ni akotan, ijọba ipinlẹ Ọyọ wa tẹnumọ pe gbogbo awọn ti ọwọ ba tẹ nidi iṣẹ ọdaran t’oun ti gbogbo dukia ti wọn ba lo lati ṣe iṣẹ laabi naa ni igbesẹ ofin to to maa jẹ ṣiṣe lori wọn.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹfa oṣu yii ni ile-iṣẹ ọlọpa ẹka tipinlẹ Ọyọ doola Iyaafin Olaide ati awọn ibeji rẹ, Peter ati Paul lọwọ awọn ajinigbe ti wọn si fi ṣikun ofin gbe awọn afurasi ọdaran ti wọn wa nidi iṣẹ laabi naa.