Lẹyin ọjọ kẹtalelogun l’akata awọn ajinigbe, Abilekọ Alamu to jẹ Olukọ Agba ọkan ninu awọn ile-ẹkọ ti ijinigbe kọlu ni ijọba ibilẹ Oriire ni ipinlẹ Ọyọ ti tun han fun igba kẹta ninu fọnran tuntun ti awọn ajinigbe-agbesunmọmi naa gbe jade lati inu igbo ti wọn gbe wọn pamọ si.
Ninu fọnran tuntun ti wọn ṣe yi ni Olukọ Agba ti n ṣalaye pe irọ patapata ni pe awọn ajinigbe naa n beere fun owo itusilẹ ati imuṣẹ ofin Ṣẹria. Alamu jẹ ko di mimọ pe iroyin ofege patapata.
Siwaju si, Olukọ Agba naa ṣalaye pe koko ohun ti wọn beere fun ni ki ijọba o da awọn ojugba awọn ajinigbe naa to wa ni akata ijọba si’lẹ, ki awọn naa o si yọnda awọn olukọ ati akẹẹkọ ti wọn jigbe.
Olukọ agba naa rọ ijọba lati ma fi ọrọ ẹmi wọn ṣe oṣelu, dipo bẹẹ ki ijọba o tete gba wọn si’lẹ