Ọmọ Iya Mi Ni Gbogbo Awọn Ilumọọka Ọkunrin L’orilẹ-ede Naijiria – Tems

Ọmọ Iya Mi Ni Gbogbo Awọn Ilumọọka Ọkunrin L'orilẹ-ede Naijiria - Tems

Gbajugbaja onkọrin ‘binrin to ti gba ami-ẹyẹ Grammy, Temilade Openiyi ti gbogbo eeyan mọ si Tems, lo ti ṣalaye idi t’oun o ṣe le fẹ tabi sunmọ awọn ilumọọka l’ọkunrin l’orilẹ-ede Naijiria fun ọrọ fifẹ.

O sọ eyi ni idahun si ibeere nibi ifọrọwanilẹnuwo kan nigba ti wọn bi boya o le kọ’nu ifẹ si aṣọle ikọ agbaojẹ ilẹ wa, Maduka Okoye pẹlu bo ṣe dun ri l’ọmọ ọkunrin.

Tems ni, nitori o jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria, oun o le ri bẹẹ laye. O ṣalaye pe ko wun oun lati ṣe wọle-wọde pẹlu ilumọọka kan-kan l’orilẹ-ede Naijiria nitori oun ri wọn gẹgẹ bii ọmọ iya.

O ni lootọ, oun mọ ẹni ti Maduka jẹ bi o ti lẹ jẹ pe oun o mọ de’le, ṣugbọn oun o le da ẹnu ifẹ ko. O fi kun pe ebi kan-naa ni gbogbo awọn ilumọọka l’orilẹ-ede Naijiria.

 

Tems lo ja gbangba nidi orin ninu oṣu kẹjọ ọdun 2019. Ọdun 2023 lo gba ami-ẹyẹ agbaye Grammy fun ipa rẹ ninu orin Drake.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search