Ọpẹlọpẹ Iṣẹ Orin, Mi O Ba Ma Ni Iṣẹ Lapa - Ayra Starr
Ilumọọka onkọrin ‘binrin, Oyinkansola Sarah Aderibigbe ti gbogbo eeyan mọ si Ayra Starr, lo ti ni pe o ṣeeṣe k’oun ma ni iṣẹ lapa ti oun o ba ja gbangba l’agbo amuludun, to si n gboriyin fun irin-ajo rẹ nidi iṣẹ orin pe ohun lo yi igbesi aye oun pada.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ kan lo ti ka aka sẹyin lori bo ṣe goke di gbajugbaja, irin-ajo rẹ pẹlu Mavins ati ohun ti oju rẹ ti ri gẹgẹ bi ilumọọka.
O ni ti oun o ba jẹ onkọrin, oun o le ni iṣẹ lọwọ, koda oun o lero pe oun le jẹ agbefọnranjade l’ori ayelujara gan nitori iṣẹ naa a ti pọju f’oun. O tẹsiwaju pe o ṣeeṣe k’oun maa jẹ ounjẹ iya oun n’ile rẹ.
Ayra Starr ṣe iranti bi inu rẹ ṣe dun nigba ti o gbọ pe Don Jazzy ati awọn ikọ Mavin ti n gbọ orin rẹ ko to di pe o darapọ mọ wọn.
O gba pe lootọ jijẹ olokiki maa n ni ipenija, to si ni pe nigba mii, o maa n wun oun ki awọn eeyan ma mọ nkan pupọ nipa oun nitori, oun maa n sọrọ lẹkunrẹrẹ nibi ifọrọwanilẹnuwo.
Ayra Starr lo darapọ mọ Mavins ni ọdun 2020 lẹyin ti Don Jazzy ṣe awari rẹ lori ẹrọ ayelujara. Lati igba naa lo ti gbina ya nidi iṣẹ orin gẹgẹ bi ọkan lara awọn olorin to n gbe ogo orilẹ-ede Naijiria ga kaakiri agbaye, pẹlu bo ṣe ti gba ami-ẹyẹ l’oriṣiriṣi ni’lẹ yii ati l’oke okun.