Mo Jale Ri Ni Kekere – Charly Boy

Mo Jale Ri Ni Kekere - Charly Boy

Ajijangbara ati amuludun lorilẹ-ede Naijiria, Charles Oputa, ti gbogbo eeyan mọ si Charly Boy lo ti ṣaṣọloju bo ṣe gbe igbe-aye ọdaran nilu Amẹrika nigba to ṣi kere.

Charly Boy lo jẹwọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan. O ni nigba t’oun kere, oun ṣe awọn ipinnu kan to buru jai leyi to jẹ pe bi oun ṣe n w’ẹyin wo, abamọ lo jẹ f’oun.

 

O ni oun ti ṣe awọn ọpọlọpọ aṣiṣe, koda, oun jale ri nigba kan. O fi kun pe nitori ohun ti Ọlọrun fẹ fi oun ṣe l’oun ṣi ṣe wa, bi bẹẹ kọ, oun o ba ma le joko nibi ifọrọwanilẹnuwo naa.

O tẹsiwaju pe kaka k’oun fi awọn nkan yẹn pamọ, oun fẹ fi kọ iwe itan igbesiaye oun lati fi irin-ajo t’oun rin lati ipanle de ayipada rere han.

 

Charly Boy ti awọn eeyan tun maa n pe ni Area Fada lo ja gbangba nidi orin ni ọdun 1985.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search