Ẹ Ma Pe Mi Ni Oṣere Mọ, Ko Pe Mi Rara- Ayọbami Ojo Pa'riwo
Arẹwa oṣerebinrin Ayọbami Oyinkan Ojo to kopa ninu sinima olokiki nni “Luwo Gbagida” lo ti pa’riwo si’ta pe ki aye ma pe oun ni oṣere mọ nitori ko pe oun rara, ko iya nla lo n ko jẹ oun.
Ninu fọnran ti oṣere yii ti awọn miiran mọ si Oyita abi Luwo Gbagida fi si’ta l’ori ayelujara lo ti n f’ara ya pẹlu ibinu ni gbogbo ara rẹ ohun ti oju rẹ ti kan nitori pe o jẹ oṣere tiata.
Obinrin naa pe aimọye ni anfaani olowo iyebiye to ti bọ mọ oun l’ọwọ nitori pe wọn ni oṣere l’oun. Bi apẹẹrẹ, l’ọdun to kọja, Ayọ ni oun fẹ ra dukia kan, ti gbogbo ẹ si ti bọ si, kinni wọn gbọ pe oṣere ni oun si, ni gbogbo ẹ ba fọ’ju pọ. Iru rẹ tun ṣẹlẹ ni’gba ti oun fẹ gba ṣọọbu kan naa laipẹ yii.
Oṣerebinrin yii ko ma’ra duro rara, ninu fọnran yii kan-naa lo ti ta si awọn af’oju-fẹ’ni-ma-f’ọkan-fẹ’ni to jẹ pe wọn ma n ba awọn oṣere jẹ l’ẹyin wọn. O tun ṣe apẹẹrẹ bi anti kan ti oun mọ ṣe ba oun jẹ ni’waju ọkunrin to fẹ d’ẹnu ifẹ kọ oun, o ni anti naa pe oloogun ika l’awọn oṣere, bẹẹ kẹ anti naa a ma fi ifẹ han si pupọ l’ori ayelujara ṣugbọn to ti f’oju han pe ko de’nu.
Paripari rẹ, o ni iyalẹnu nla ni f’oun pe awọn eniyan a ma fẹ awọn gbajumọ oṣere l’oju l’ẹnu ṣugbọn biri ni wọn a yi oju pada si iru oṣere bẹẹ bi wọn ba gbọ pe o ṣe aṣiṣe kekere, wọn a wa da bi ọta ti o f’oju han tẹlẹ, to kan n duro de aṣiṣe.
Ko ṣai bu ọrọ jo awọn ti wọn ma n ri ti awọn oṣere wi, o ni ohun ti awọn miiran wọn ṣe ti wọn a mu jẹ, bi oṣere kan ba danwo, ariwo a gba ilu kan. Ọpọlọpọ awọn oṣere akẹgbẹ rẹ bii Bimpe Akintunde, Toyọsi Adesanya, Mimisọla Daniels l’aarin awọn miiran na ti ka’wọ ti oṣerebinrin yii l’ẹyin n ṣe lo sọ oju abẹ ni’ko ni’pa ilakọja awọn oṣere.