Lẹyin Idaṣẹsilẹ Oṣu Kan, Awọn Olukọ Nipinlẹ Ọyọ Yoo Pada Si Yara Ikẹkọ
Ẹgbẹ awọn olukọ ẹka tipinlẹ Ọyọ ti f’igi gun idaṣẹ silẹ wọn kaakiri awọn ile-iwe ijọba nipinlẹ naa, ti wọn si paṣẹ ki awọn olukọ pada si yara ikẹkọ l’ọjọ Ọjọbọ.
Eyi lo tẹle awọn ipade pẹlu ijọba leyi ti wọn fi f’ọkan wọn balẹ pe wọn ti ṣe’to aabo to peye f’awọn ile-ẹkọ gbogbo lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọ ati olukọ to waye nijọba ibilẹ Oriire.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa ati akọwe ẹgbẹ buwọlu loni, wọn ni aṣẹ naa wa lat’ọdọ awọn adari ẹgbẹ naa lẹyin ti wọn ṣe atunyẹwo ọrọ aabo t’oun ti irawọ ẹbẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ati awọn tọrọ kan.
Ẹgbẹ naa wa paṣẹ fun gbogbo awọn olukọ ni ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ati sekọndiri lati pada si ẹnu iṣẹ l’ọla, ti ṣe ọjọ keji oṣu yii.
Iwọle yii yoo jẹ opin idaṣẹsilẹ ti ẹgbẹ naa kede lẹyin ijinigbe awọn olukọ ati akẹkọọ nijọba ibilẹ Oriire.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, wọn ṣe ipinnu yii fun anfaani awọn olukọ, akẹẹkọ ati gbogbo awọn araalu pata lẹyin ti ijọba ti fi wọn lọkan balẹ pe igbesẹ n lọ lọwọ lati doola awọn ti wọn wa l’akata awọn ajinigbe, ati lati ri pe aabo to dunju wa l’awọn ile-ẹkọ gbogbo ati agbegbe wọn.
Ẹgbẹ naa wa rọ awọn olukọ lati ni ifura, ki wọn tẹle ofin ati pe o ṣe pataki ki wọn fi to ijọba leti ti wọn ba ko firi nkan to ṣeeṣe ko koba eto aabo.
Ni ipari, wọn fi ọwọ sọ’ya pe wiwa ni alaafia awọn olukọ jẹ awọn logun gan, bẹẹ ni wọn n tẹnpẹlẹ mọ pe awọn a tubọ maa ba ijọba sọrọ lati ri pe, gbogbo nkan to ni ṣe pẹlu aabo awọn olukọ ati akẹkọọ ni wọn ṣiṣẹ le lori.
Ọjọ kẹẹdogun oṣu karun-un ni awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ṣe ikọlu si awọn ile-iwe mẹta ọtọọtọ nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ ti wọn si ko awọn olukọ ati akẹkọọ to le ni ogoji lọ.
Lẹyin iwọde alalaafia lati fi aidunnu wọn han, ẹgbẹ awọn olukọ ni ipinlẹ Ọyọ da iṣẹ silẹ ni ọjọ kini oṣu kẹfa ọdun yii.