Owo Rederede Ti Wọn N San Lo Mu Mi Kuro Ni’di Sinima Tẹlẹ – Deyemi Okanlawon

Owo Rederede Ti Wọn N San Lo Mu Mi Kuro Ni'di Sinima Tẹlẹ - Deyemi Okanlawon

Gbajugbaja oṣerekunrin, Deyemi Okanlawon lo ti ṣaṣọloju idi to ṣe pa ṣiṣe sinima ti tẹlẹ. Nigba to n sọrọ lori irin-ajo ati iriri rẹ gẹgẹ bi oṣere nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lo ti ni oun fi ṣiṣe sinima silẹ fun igba diẹ ni ọdun 2019.

Deyemi ni oun fi iṣẹ naa silẹ nigbayẹn nitori wọn o san owo gidi bẹẹ ni iṣẹ naa ri rederede nigba naa eyi lo jẹ k’oun ro pe, oun o f’iṣẹ ọfiisi silẹ lati maa ṣe iṣẹ ti ko bu’yi kun oun.

O fi kun pe, o nira fun oun lati ji lọ si ibi iṣẹ nigba naa. O ni kini anfaani pe eeyan n’ifẹ si iṣẹ kan nigba ti ko mu ayọ ati idunnu wa.

Deyemi tẹsiwaju pe, nitori rẹ l’oun ṣe fi ṣiṣe sinima silẹ t’oun dẹ pada si’di iṣẹ ọfiisi t’oun n ṣe tẹlẹ.

Deyemi Okanlawon lo ja gbangba gẹgẹ bi oṣere ni ọdun 2013 lẹyin bii ọdun mẹwa lẹka itaja ile-iṣẹ. Nigba to di ọdun 2019, o kuro l’agbo sinima fun igba diẹ, ko to pada de ni ọdun 2020.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search