Agbabọọlu ikọ agbaojẹ orilẹ-ede Naijiria, Victor Osimhen ti ni oun ni l’ọkan lati pada si ile-iwe fasiti lati k’ẹkọ gboye pẹlu bo ṣe ti laluyọ nidi bọọlu alafẹsẹgba.
Osimhen sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan. O ni lootọ, ile-aye ti kọ oun l’ẹkọ ti oun o le mọ ni yara ikẹkọ kan-kan ṣugbọn o ṣi wu oun lati k’ẹkọ iwe ko le pe.
O ṣalaye pe lootọ, bọọlu gbigba ti tun aye oun ṣe ṣugbọn oun mọ pe ko lẹ jẹ titi laye. O ni lẹyin bi ogun ọdun tabi ọdun mẹẹdọgbọn, eeyan a pari iṣẹ rẹ n’idi bọọlu.
Agbabọọlu naa ni, ọkan lara iwuri oun lati k’ẹkọ ni ki oun le jẹ awokọṣe rere fun awọn ti wọn fi ẹkọ silẹ yala nitori owo ni tabi awọn ipenija mii. O ni oun fẹ ṣafihan pe, ki eeyan fi ile-iwe silẹ ko tumọ si opin irin-ajo ẹkọ.
Osimhen ti wọn bi ni ipinlẹ Edo l’orilẹ-ede Naijiria lo jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu ilẹ wa to n lewaju l’agbaye. O gba ami-ẹyẹ oke okun alakọkọ ni ọdun 2015 nigba to ṣetan gẹgẹ bi ẹni to mi awọn ju ninu idije FIFA fun awọn ti wọn wa labẹ ọdun mẹtadinlogun, to si ba orilẹ-ede Naijiria gbe ife.
Ọrọ to sọ yii ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti fi kin lẹyin pe, ootọ ni nitori ẹkọ ṣe pataki.