Gbajumọ alufa ninu ẹsin Islam Sheikh Ahmad Gumi ti sọrọ lẹyin idakẹ ọjọ pipẹ lori abẹwo rẹ s’ilu Ibadan l’opin ọdun to koja pẹlu bi ọpọ awọn eeyan ṣe n binu pe o fẹ sọ ipinlẹ Ọyọ di ti ẹsin Islam pẹlu awọn igbe-aye awọn ara ẹkun ariwa to fẹ gbe wọle.
Gumi tẹnpẹlẹ mọ pe ko si ẹni to le da oun duro lati ma de ibikibi lorilẹede Naijira bẹẹ lo n duro lori pe kii ṣe ẹgbẹ musulumi kankan abi ẹnikẹni ni ẹkun guusu iwọ-oorun lo f’iwe pe oun.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ lo ti ni oun wa si Ibadan gẹgẹ bii aṣoju awọn omowe islam l’ẹkun ariwa.
Ọrọ Gumi yi lo waye lẹyin ti fọnran ọkan lara awọn olukọ ti wọn jigbe nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ jade. Ninu fọnran ọhun lo ti kọ awọn iroyin l’agbọn kan pe awọn ajinigbe naa n beere fun ofin Sharia nipinlẹ Ọyọ ati owo biliọnu kan naira pe irọ to jina si ootọ ni nitori nkan ti wọn n beere ni ki wọn fi lara awọn eeyan wọn ti wọn wa ni ẹwọn silẹ.
Bẹẹ ni ajọ Muslim Rights Concern (MURIC) naa kọ iroyin naa pe irọ lati inu jahannamoh ni ati pe awọn ti wọn fẹ ba Islam loju jẹ ni wọn wa nidi iroyin naa.
Nigba to n sọrọ ti ajọ MURIC lẹyin, Gumi ni o ye oun bi ibẹru islam ni ipa lori oṣelu ẹkun guusu iwọ-oorun ati idi ti wọn fi wọ oun sinu eto oṣelu booba-o-pa-booba-o-bu-lẹsẹ lọna aitọ.
O ni oun wa s’ilu Ibadan gẹgẹ bii aṣoju awọn ọmọwe nipa ẹsin Islam ni ẹkun ariwa kii ṣe pe ẹnikẹni abi ajọ kankan pe oun. O wa pari ọrọ rẹ pẹlu ibeere pe njẹ ẹnikẹni le da oun duro lati ma lọ si ibikibi lorilẹede Naijira bii?
Ti ẹ o ba gbagbe, Gumi ṣabẹwo silu Ibadan ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ọdun to kọja nibi to ti jẹ alejo pataki ati ọkan lara awọn sọrọ-sọrọ nibi apejọpọ Southern Nigerian Ulama Summit to waye ni Fasiti Ibadan.