PORTABLE ỌLALỌMI TUN TI S’ỌRỌ ṢAKAṢAKA SI BADDO

Laarin bi ọpọ awọn eniyan ti n ba Ọlamide Adedeji iyẹn Ọlamide Baddo da muso fun aṣeyọri ipatẹ ere rẹ ni’lu London ni tuntun miiran tun ru’gbo ja’de.

Eegun Portable Ọmọ Ọlalọmi lo ma tun s’ọrọ bi agbọn. L’ori ikanni Instagram rẹ lo ti n d’ọgbọn bu ọrọ jo Ọlamide ti eyii kii si ṣe igba akọkọ. Botilẹjẹpe ko darukọ Ọlamide taara ninu eyi, ṣugbọn awọn akawe ati afiwe to ṣe paapaa julọ pẹlu orin “Zazu Zeh” to mẹnuba iyẹn orin to gbe ogo Portable ja’de fun gbogbo aye, eleyii ti Ọlamide ati Poco Lee iyẹn gbajumọ “araparegangan” onijo dijọ ko’pa ninu rẹ.

Portable ni Baddo ko ran oun l’ọwọ rara t’ori ogo ni oun l’aaye ara oun tẹlẹ tẹlẹ. Koda oun ni oun fi ina ogo oun ran ti Baddo to fi tun jo geere lati di ogo agbaye.

Ọrọ pọ ti Ọmọ Ọlalọmi mẹnuba ninu awọn fọnran ṣe ninu ọkọ kan to nlọ bii meedogun (15) to gbe s’ori ikanni Instagram rẹ @portablebaeby. “Werey Olorin” yi ni Aguda t’oun ko jẹ l’abẹ Gẹẹsi nítorí n ṣe ni Ọlamide kan fun oun ni faasi (verse/awẹ orin) lasan ni ti ko dẹ jubẹ lọ.

“Awọn fansi (fans/ololufẹ) mi naa fun mi l’owo, awọn naa gbe mi lọ si ilu oyinbo… To ba jẹ hẹpa (helper/oluranlọwọ) mi, wa maa gbe aago mi…Ẹ o le pa mi bẹ ṣe pa 2pac, ẹ o le pa mi bẹ ṣe pa Imọlẹ (Mohbad) mo ti s’ọrọ s’oke…

Awọn fansi mi na ni ki n ma s’ọrọ lati fi ẹnu gba ogo mi si’lẹ” Wọnyi jẹ diẹ ninu ọpọ pẹtẹpẹtẹ ọrọ lile ti Portable na ni pọpa l’ori ayelujara.

Portable o tun ṣai ṣe ileri pe oun bọ lati ri ogo nla lo daadaa ju bayii lọ t’ori oun ni “Olorin Igbalode.” Ọmọ Ọlalọmi ti wa fun Baddo ni wakati mẹwaa lati tọrọ aforijin pe ko pe oun wa si London fun ti ipatẹ orin rẹ iyẹn konsati (concert) to ṣẹṣẹ pari bi bẹẹ kọ ọrọ ko ni rọgbọ.

Ni bayii, ero awọn eniyan l’ori ayelujara ati ni’gboro lo s’ọtọtọ l’ori Ọmọ Ọlalọmi, awọn kan ni iwa ikọja aaye, aimoore ati inunibini gba ni Portable wu bẹẹ ni awọn kan gbagbọ pe ko si laifi lati fi ẹnu gba ara ẹni si’lẹ, pe ọna ọtọtọ ni oju opo iṣerere kaluku.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search