Ẹ Lọ Wa Iṣẹ Ṣe, Fọnran To Ti Pẹ Lẹ N Gbe Kiri - 2Baba
Agbaojẹ onkọrin takasufe, Innocent Idibia ti gbogbo eeyan mọ si 2Baba, lo ti jade sọrọ lori fọnran to n tan ka eyi to n ṣafihan oun ati iyawo rẹ tẹlẹ, Annie, nibi ti wọn ti n ṣ’ere ifẹ.
Fọnran naa lo ṣafihan awọn ololufẹ tẹlẹ mejeeji naa ti wọn jọ n yo ife ninu kilọbu.
Lẹyin ti fọnran naa tan ka ni ọpọ awọn eeyan ati awọn gbajugbaja ti wọn gbe lẹyin ẹni kọọkan wọn nigba ti ọrọ ituka wọn ṣẹlẹ fi iyalẹnu wọn han lori rẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ ni Annie ti ko ọrọ naa danu pe kii ṣe ootọ. O ni ki awọn eeyan ma gba gbogbo nkan ti wọn ba ri lori ayelujara gbọ nitori fọnran naa ti pẹ.
Nigba to n sọrọ lori fọnran naa, agba onkọrin ọhun lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ fi ontẹ lu pe fọnran to ti pẹ ni fọnran to n tan ka naa.
Ọrọ ifẹ awọn mejeeji jẹ ọkan gboogi l’agbo amuludun nitori ọdun 2002 ni wọn bẹrẹ ọrọ ifẹ wọn. Ọpọ igba ni awọn mejeeji tuka latari pe 2Baba yan ale l’oriṣiriṣi ti awọn obinrin meji si bi ọmọ mẹta fun.
Pẹlu pe Annie lo kọkọ bẹrẹ sii fẹ, ọmọ ti Annie bi ni ikarun fun 2Baba. Ọdun 2013 ni 2Baba ati Annie ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu gbogbo rogbodiyan ọrọ ifẹ wọn.
Laarin 2021 si 2022 ni awọn mejeeji ja lori ayelujara nitori ale yiyan ati awọn ẹbi 2Baba pẹlu bi Annie ṣe sọ.
Inu oṣu kini ọdun to kọja ni 2Baba kede pe awọn mejeeji o si papọ mọ.
Ọrọ yii lo fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara fun awọn ololufẹ awọn mejeeji ti awọn kan n gbe lẹyin Annie nigba ti awọn kan gbe lẹyin 2Baba.