Ko jẹ tuntun mọ pe ọrẹminu pataki ni Rotimi Salami jẹ si irawọ oṣere ati adari ere, Allwell Ademọla to da gbere f’aye ni ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2025 to kọja, ti ọpọ si n wo ibi ti Rotimi yoo fi oju si lẹyin iku Allwell botilẹjẹpe Rotimi ko ti sọ nkankan lọ titi.
L’ọwọ yii, Rotimi Salami ninu fọnran kan l’ori ikanni Instagram ti wa bọ si’ta lati sọ’rọ ni’pa ipapoda Allwell ati ẹdun ọkan ti ko jẹ ki o sọ’rọ lati igba yii wa. O ṣ’alaye pe “N ko fẹ bu si ẹkun ni mo ṣe n dakẹ, mo si ti ṣe’leri pe n o ni bu si’gbe.” Bẹẹ bi ọkunrin naa ṣe n sọ’rọ l’omi n le roro s’oju rẹ ṣugbọn to n tirika lati ma sun’kun.
Ẹdun ọkan ti Rotimi tọka si ninu fọnran naa ni pe, iṣẹ kan n bẹ ti awọn mejeeji iyẹn Rotimi ati Allwell ti jọ ṣe pamọ ṣugbọn ti fiimu naa ko ti ja’de fun wiwo. Rotimi juwe iṣẹ gẹgẹ bii ere sinima nla ti yoo p’okiki Allwell to jẹ adari ere naa ti oun jẹ olootu rẹ nitori oun ti kọkọ ba Allwell sọ’rọ ni’pa gbigbe ere sinima nla ja’de ṣugbọn ti Allwell ni asiko ko ti to, l’eyi to fa ki oun lọ ṣe akitiyan l’ori inawo ati wiwa onigbọwọ ṣugbọn to jẹ pe Allwell ni adara ere sinima naa.
Rotimi ṣ’alaye siwaju si pe “Kilanko: The Invincible Child” ni akọle ere alagbara naa ṣugbọn to jẹ ẹdun ọkan pe Allwell ko si l’aye mọ lati gba gbogbo oriyin to tọ fun iṣẹ takuntakun naa. Rotimi pe “Eniyan meji ni erongba ati ṣe oun rere to l’agbara ṣugbọn ẹnikan pere ninu wọn lo sẹku (l’aye) bayii.” O wa rọ awọn ojugba rẹ, awọn oṣere, ati awọn ololufẹ lati sugba ere sinima nla naa to n bọ lọna, ti ifilọlẹ yoo wa’ye ni ọjọ kinni oṣu mẹta (March 1st), ti yoo si ja’de fun wiwo ni awọn ile iworan (cinema) ni’lẹ yii bẹrẹ lati ọjọ kẹta oṣu kẹta (March 6th).
L’ọwọ yii, ọgọrọ awọn ololufẹ, alatẹle ati awọn oṣere gan-an paapaa lo ti n fi ifẹ han l’ori iṣẹ naa ati ṣiṣe aduroti to yẹ.