Lẹyin Ti Aṣakẹ Olorin Ra Ọkọ F’awọn Obi Rẹ, Lo Ba Tun Lọ Humura Lọ Fọwọ Kan Kahaba

Gbajugbaja irawọ olorin ọmọ ilẹ wa nni, Ọlọlade Ahmed Aṣakẹ ti ọpọ mọ si Aṣakẹ abi Ọlọlade Mr Money lo ṣe ohun meeriri, olorin naa lo gbe gbogbo afẹ ati ọrọ aye to ni s’ẹgbẹ kan, to si lọ re jọsin f’Oluwa ni orilẹ-ede Saudi Arabi l’ọhun lati kopa ninu eto Humura to n lọ l’ọwọ.

N ṣe ni fọnran ati aworan Aṣakẹ lu ori ayelujara pa ninu aṣọ funfun ti wọn ma n wọ ni ilẹ mimọ Mecca ati Medinah l’asiko iṣẹ Hajji abi Humurah. Koda ninu fọnran kan lati ri Aṣakẹ ti wọn gbe s’oke sunmọ Kahaba, t’oun naa si n jà rabu-rabu lati le f’ọwọ ba ara Kahaba.

Ko tan sibẹ, ba ti gaani Aṣakẹ, ni awọn ẹni igba oju mọ miran naa wa pẹlu rẹ ti wọn jọ ṣe irin-ajo ẹmi naa, ninu wọn ni Rahman Jaga, to n naa jẹ alafẹ ati amuludun, bẹẹ la tun ri ọgbẹni Muyideen Ọladapọ ti ọpọ mọ si Lala to jẹ gbajugbaja oṣere tiata ati adari ere, to tun jẹ ẹgbọn to sunmọ Aṣakẹ daadaa lati ilẹ wa.

Ẹ ranti pe Aṣakẹ lẹyin to dari de si orilẹ-ede Naijiria lati orilẹ-ede Amẹrika to gbe fun igba diẹ lo ti n farahan daadaa l’aarin igboro Eko ati ilẹ Yoruba lapapọ, bẹẹ lo la tun kẹfin rẹ ṣaaju asiko ni mọṣalaṣi nla Jimoh kan niluu Eko to fihan pe Aṣakẹ ti n gbaradi fun ṣiṣe abẹwo si ile Oluwa lati igba diẹ sẹyin.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search