GBẸGẸDẸ GBINA, ILE-ẸJỌ NI KI AJỌ INEC YỌ ẸGBẸ NDC DANU

GBẸGẸDẸ GBINA, ILE-ẸJỌ NI KI AJỌ INEC YỌ ẸGBẸ NDC DANU

Ile-ẹjọ giga apapọ kan to joko s’ilu Lọkọja l’oni ọjọ Ẹti (Friday) ti gbe idajọ kan to ti kọkọ ṣe l’atẹyin wa s’ẹgbẹ, to si ti fi aṣẹ tuntun miiran le’lẹ l’ori ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC), ti ṣe ẹgbẹ ti Peter Obi ati Rabiu Kwankaso ti n dije du ipo aarẹ ati igbakeji.

Aṣẹ tuntun yii lati ẹnu Ondajọ Isah Dashen ni ile-ẹjọ fi pa’ṣẹ ki ajọ INEC wọ’gi le orukọ ẹgbẹ oṣelu NDC l’asiko yii naa titi ti wọn yoo fi gbọ ọrọ l’ẹnu gbogbo awọn t’ọrọ kan l’ori ẹjọ naa.

Ile-ẹjọ lo gba pe lootọ ni o yẹ ki awọn gbọ lati ẹnu ẹgbẹ kan ti wọn pe ni PMP iyẹn Peace Movement Party nitori awọn naa ni ṣe pẹlu ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu NDC n koju l’ọwọ.

Ni’woye Onidajọ naa, idajọ at’ẹyin wa naa to sọ pe ki wọn da ẹgbẹ oṣelu NDC mọ gẹgẹ ojulowo ẹgbẹ oṣelu lo ni aayẹ nitori idajọ naa wa’ye lai gbọ ọrọ pe lati ẹnu gbogbo awọn t’ọrọ kan, ti ifojufo naa si ti sọ gbogbo igbesẹ ati idajọ at’ẹyin wa di ohun ti ko ni itẹwọgba.

Onidajọ Dashen tun pa’ṣẹ ki gbogbo nnkan o pada si ipo to wa ṣaaju idajọ ọjọ kẹwaa oṣu kejila ọdun 2025 (10th, December 2025), titi di igba ti gbogbo ẹjọ naa yoo yanju lodindi.

Gẹgẹ bii aabọ iroyin ajọ akoroyin jọ NAN ṣe wi, agbẹjọro olupẹjọ, Chikezie Ekeocha, sọ f’awọn oniroyin pe ẹgbẹ PMP lo tọ ile-ẹjọ lọ lẹyin ti wọn ṣ’akiyesi pe ami idanimọ ti ẹgbẹ NDC fi ṣe iforukọsilẹ ni awọn ti kọ fi s’ọwọ si ajọ INEC kii igbẹjọ o to bẹrẹ.

L’at’ari eyi, ile-ẹjọ ti pa’ṣẹ ki wọn o lọ tun ẹjọ naa ko pada ni tuntun lati ibẹrẹ pẹpẹ, pẹlu ajọ INEC, ẹgbẹ PMP ati ẹgbẹ NDC to jẹ awọn ti ọrọ ẹjọ naa kan.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search