Alaye awọn kan ni pe DJ Tunez to jẹ alasunmọ ati alabaṣiṣẹpọ Wizkid ti kọkọ wa ni ile-ijo (Night Club) ti ariya naa ti waye ṣaaju ki Burna Boy ati awọn eniyan rẹ naa wọle.
Ẹwẹ, ariyanjiyan kan ni oṣojumikoro lo waye laarin awọn mejeeji, ti ọrọ naa si sare di ariwo, l’eyi to mu ki Burna Boy ta DJ Tunez l’aya, ti DJ Tunez naa si fi ẹsẹ gbona pade Burna Boy, ti awọn to wa ni itosi si tete mu Burna pada sinu ọkọ rẹ, ṣugbọn ti Burna kan pada de lojiji pẹlu awọn gidiganku bi melo kan, Burna atawọn eeyan naa lo pawọpọ fiya jẹ DJ Tunez.