Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham Ajeyemi lo ti fọ esi ọrọ pada si awọn t’oun pe ni alabosi nitori pe oun kunlẹ ẹsẹ mejeeji fun gbajugbaja parakoyi, Razaq Ọkọya ti ọpọ mọ si Eleganza ati aya rẹ Ṣade Ọkọya ati awọn agbagba kan lode ariya kan to waye laipẹ yii.
Toyin lo ṣe alaye yii l’ori ikanni Instagram rẹ pe oun kii ṣe alabosi ẹda nitori ikunlẹ fawọn to ju oun lọ. O ni abuda oun gẹgẹ bi ojulowo ọmọluabi ni lati ma kunlẹ fawọn to ba ti ju oun lọ.
Fọnran ibi ti Toyin ti ki Oloye Ọkọya, aya rẹ – Ṣade, ati akọle kan to kọ sabẹ aworan pe “gẹgẹ bii ọmọluabi, n o ma gbe aṣa ati iṣẹ larugẹ” ni ọpọ awọn eniyan ri ti awọn kan ninu wọn si bẹrẹ si ni fẹnu ṣata Toyin pe alabosi ni.