Arẹgbẹṣọla, Peter Obi, Kwankaso At’awọn Miran Ṣe Iwọde L’Abuja

Ero witi lo jade nibi ifẹhonuhan ti ẹgbẹ oṣelu ADC ṣe si ọfisi ajọ eleto idibo INEC nilu Abuja, lonii ọjọru Wednesday lai wo bi ojo ti n rọ.

Ifẹhonuhan naa to da le ori wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC lo rọra bẹrẹ ranpẹ lat’ọwọ igun ti David Mark ati Rauf Arẹgbẹṣọla jẹ alakoso rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Kẹrẹ kẹrẹ lo di ohun ti awọn eniyan miran ati awọn oloṣelu miran ninu ẹgbẹ oṣelu alatako da si.

Awọn oloṣelu ṣanko-ṣanko ninu ẹgbẹ naa bi Peter Obi, Rauf Arẹgbẹṣọla, Rabiu Kwankaso lo le iwaju awọn olufẹhonuhan naa. Awọn patako ti wọn gbe dani lo ni akọle “Tinubu, jẹ ki oṣelu awarawa o ri’mu mi.”
Ẹwẹ, igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima ni Peter Obi abi ẹnikẹni ko le ko ijọba ni papa mọra lati ja ijọba gba abi fi ọna ẹbẹru de’po. Ni bayii, oniruuru iwoye lo ti lu igboro pa l’ori ifẹhonuhan naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search