Minisita fun Ọrọ-aje ati Iṣuna lorilẹede Naijira, Taiwo Oyedele ti sọ pe ijọba apapọ o ni da owo iranwọ pada tabi kan nipa fun ẹnikẹni lati ta ọja wọn ni iye kanna nitori pe iṣẹ akanṣe ti yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje jẹ iṣejọba yii logun.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan ni Paris lorilẹede France lẹyin apero kan pẹlu awọn oludokowo lagbaye, Oyedele ni ohun to jẹ ijọba logun ni lati sa fun awọn ofin to le da ọrọ aje ru ati lati tẹnpẹlẹ mọ awọn eyi to le daabo bo awọn araalu.
Oyedele ni bi o tilẹ jẹ pe ko si dida pada owo iranwọ tabi kikan iye owo itaja kan naa nipa fun gbogbo eeyan nitori awọn n’igbagbọ ninu ọja tita ṣugbọn iṣejọba yii a rii pe ko si ẹnikẹni to maa yan awọn ọmọ orilẹede Naijiria jẹ yala ile-iṣẹ to n pese ọja ni tabi ontaja.
Minisita fun Ọrọ-aje ati Iṣuna lorilẹede Naijira, Taiwo Oyedele
O ṣalaye pe iṣejọba yii n fi ọkan si ṣiṣe eto eleyi ti yoo mu ki awọn onraja maa tọka si bi ọja yoo ṣe jẹ tita lọna ti ko ni pa ẹnikẹni lara. O wa tọka si awọn idagbasoke kaakiri agbaye ati bi ogun to n ṣẹlẹ ni Iran ṣe n fa idojukọ fun awọn anfaani lorilẹede Naijira paapaa julọ lẹka ohun amuṣagbara.
Oyedele wa fi idunnu rẹ han wipe pẹlu bi ọrọ aje orilẹede Naijiria ṣe n lọ ọjọ-ọla rere wa fun orilẹede yii.
Ọrọ Oyedele yii n ṣafihan erongba ijọba pẹlu bi ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣe n fi aidunnu wọn han lojoojumọ lori owo iranwọ ti wọn yọ ati bi gbogbo nkan ṣe n fi ojoojumọ gbe owo lori si.