Kayefi! Wọn Le Peter Obi Kuro Ninu Ẹgbẹ Obidient Movement

Adije du ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour (LP) ninu eto idibo gbogbogbo to waye kọja l’ọdun 2023, Ọgbẹni Peter Obi ni wọn ti le kuro bayii ati awọn ṣanko-ṣanko miiran ninu ẹgbẹ awọn ololufẹ ati alatẹle Peter Obi, ti wọn n pe ni “Obidient Movement.”

Ikede naa waye lonii (Ọjọbọ Thursday) ni ilu Abuja nibi ti wọn ti fi ọrọ naa to awọn oniroyin l’eti, ti wọn si ṣe agbedade ẹgbẹ naa gẹgẹ bii eyi to ti gbe awọ tuntun wọ, ti wọn si tun ta kete si awọn kọọkan ninu ẹgbẹ pẹlu ẹsun pe wọn ti ta’sẹ agẹrẹ nitori iwa imọtaraẹni-nikan kuro l’ori ohun ti ẹgbẹ “Obidient Movement” duro fun.

Ọgbẹni Peter Obi

Ni’gba to n s’ọrọ ni’bi eto naa, Alakoso Kaari-aye fun ikọ abi ẹgbẹ “Obidient Movement,” Barry Avotu Johnson jẹ ko di mimọ pe o ṣe pataki fun awọn lati jina si Peter Obi ati awọn eekan miiran ninu ẹgbẹ naa l’ẹyin eto idibo ọdun 2023.

Gẹgẹ bii o ti wi, o ṣalaye pe awọn to n tu’kọ ẹgbẹ naa lati ẹyin idibo to lọ ti ya bara kuro l’oju ọna oun ti awọn ti itori rẹ da ẹgbẹ abi awujọ naa si’lẹ, to si ṣe pataki lati gba akoso kuro l’ọwọ wọn.

Ni kukuru, Johnson jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹ “Obidient Movement” ko ni nnkan ṣe mọ pẹlu Peter Obi; awọn ẹmẹwa rẹ ninu ẹgbẹ naa; to fi mọ ẹgbẹ oṣelu Labour (LP).

Pabambari ni pe awọn ko ti ni ayanfẹ oludije kankan fun eto idibo gbogbogboo to n bọ l’ọna l’ọdun 2027.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search