Gbajugbaja olorin lorilẹede Naijira, Adekunle Kosoko ti gbogbo eeyan mọ si Adekunle Gold lo ti jade wa sọ pe irọ patapata ni pe iyawo oun to jẹ olorin naa, Simisola Ogunleye ti awọn eeyan mọ si Simi bi ibeji ati pe ọkunrin lọmọ t’awọn bi.
Nigba to n dahun ibeere lori ifọrọwanilẹnuwo kan nilu Texas nibi ti wọn ti bi nipa ọrọ to ja rọnyin lori ẹrọ ayelujara pe o bi ibeji, Adekunle ni rara o, ọmọ ọkunrin ni awọn bi ati pe bi ẹrọ ayelujara ṣe ri niyẹn.
O tẹsiwaju pe inu oun dun lati jẹ ọkọ fun olorin ẹgbẹ oun nitoripe awọn jọ maa n jiroro. O fikun pe ọmọ awọn to jẹ ọmọ ọdun mẹfa gan ti n ṣafihan pe yoo nifẹ lati kọrin.
Ọrọ pe wọn bi ibeji yii jẹyọ kaakiri orilẹede Naijiria ati oke okun lẹyin ti Adekunle Gold fi si ori ẹrọ ayelujara rẹ pe oun beere ọmọ kan lọwọ Ọlọhun o si fi meji ta oun lọrẹ pẹlu awọran aṣọ ọmọ meji.