Wura Sọ Mi Di Akuṣẹ, Diẹ Lo Ku Ki N Maa Tọrọ Gaari L’adugbo, Ọpẹlọpẹ YouTube Lara Mi – Lanre Adediwura

Oṣere Tiata Lanre Adediwura ti jade wa sọrọ lori idi to ṣe kọ lati pada sidi sinima Wura to gbe ja gbangba tẹlẹ to fi di ilumọọka.

Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe si lori ẹrọ amohunmaworan, Lanre ni pẹlu bi sinima Wura ṣe rinlẹ to niṣe lo mu oun kuṣẹ ju tẹlẹ lọ.

O ṣalaye pe iṣẹ ti oun ṣe ko mu ere t’oun l’ero pe yoo mu jade bẹẹ ni o tun fa idiwọ lati ṣe awọn iṣẹ mii. O tẹsiwaju pe oun na ju iye ti Wura fun oun lọ to si jẹ pe oṣu mẹfa lẹyin t’awọn pari Wura, oun fẹẹ le maa tọrọ gaari lọwọ awọn alabagbe ṣugbọn ikanni YouTube lo pada gbe oun ro.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, oṣerekunrin naa ṣalaye pe lootọ o, ipa t’oun ko ninu Wura gbe oun ṣugbọn iṣẹ yẹn gan gan o pese nkan t’oun fẹ nitori ọpọ awọn ileri ni wọn o muṣẹ.

Lanre tẹsiwaju pe nigba ti awọn n sọrọ, wọn fi ọkan oun balẹ pe k’oun ma gba awọn iṣẹ mii fun gbogbo oṣu mọkanla t’awọn fi ya iṣẹ Wura leyi to fa ti oun o fi si ninu sinima House of Ga’a pẹlu gbogbo akitiyan t’oun ṣe lori iṣẹ naa.

Lanre Adediwura ti ọpọ eeyan mọ si Cobra latari sinima Wura to mu ja gbangba ni ọpọ awọn eeyan reti pe yoo pada ninu saa tuntun Wura ti wọn ṣẹṣẹ fi lede yii ṣugbọn ti ko si lara awọn oṣere sinima naa mọ. Eyi lo fa ki ọpọ awọn ololufẹ rẹ maa beere idi ti ko fi kopa ninu sinima naa mọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search