Sultan tilu Sokoto, Sa’ad Abubakar kẹta ti sọ pe ẹnikẹni to ba pa eniyan ẹgbẹ ẹ to si n ṣe Allahu Akbar yoo wọna ti yoo si jẹjọ lọdọ Ọlọhun lori iwa laabi naa.
Sultan fikun pe ọpọlọpọ iwa jagidijagan ti awọn eeyan maa n fi kọ ẹsin lọrun ko ri bẹẹ rara leyi to n fa ifurasini ati ainigbagbọ ninu ara ẹni.
O sọ eyi nibi ipade Ajọ to n risi ifọwọsowọpọ ẹsin lorilẹede Naijira eyi ti oun ati Aarẹ Ẹgbẹ Awọn Onigbagbọ lorilẹede Naijira, Daniel Okoh t’oun ti Akọwe Ijọba Apapọ Ilẹ wa, George Akume ti sọrọ.
Sultan tilu Sokoto, Sa'ad Abubakar
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni ki ẹnikẹni ma fi ojo pe Ojo nitori pe ọrọ awọn agbesunmọmi ko ni nkankan ṣe pẹlu ẹsin rara nitori naa, ka ma gbe ọrọ ẹsin wọ. O tẹsiwaju pe ọdaran pọnbele ni wọn ko si nilo ka maa pe wọn ni ọdaran musulumi tabi agbesunmọmi musulumi koda bi wọn be jẹ musulumi nitori iwa wọn tako ẹsin Islam patapata.
Sultan wa ni wahala naa ko yatọ si aimọkan bẹẹ lo n kilọ sisọ ofege ọrọ lori didari ẹsin. O ṣafikun pe bi eeyan ba mọ ede Larubawa ko tumọ si pe eeyan jẹ Alufa nitori ede lasan ni Larubawa, ẹkọ gangan lo ṣe koko.
O wa ṣapejuwe pe eeyan le lọ si ọja lati fi ado oloro pa ara rẹ ati awọn eeyan ko si pariwo “Allahu Akbar” leyi to tumọ si Ọlọrun Tobi. Sultan ni, lootọ ni Ọlọrun Tobi ṣugbọn inu ina jahannamoh ni onitọun yoo lo nitori yoo jiya ẹsẹ pipa awọn eeyan ti wọn o mọwọ mẹsẹ to gbe ẹmi wọn.
Ọrọ Sultan yii n waye lasiko ti rogbodiyan pọ lọtun losi lori pe awọn kan fẹ fi tipatipa sọ Orilẹede Naijiria di ilu Musulumi nikan leyi to si n fa ikọlu awọn onigbagbọ. Eyi ni ijọba Orilẹede Naijiria ti sọ pe irọ to jina si ootọ ni nitori ọpọ awọn Musulumi gan ti ba igbesunmọmi lọ lorilẹede yii. Bẹẹ ni wọn n fi ọkan awọn araalu balẹ pe eto aabo to mẹhe lorilẹde ko ni pẹ di ohun igbagbe.