Olu ile-iṣẹ ajọ alaabo ilẹ wa ti f’ọrọ lede pe ijinigbe to waye laipẹ yii nipinlẹ Ọyọ ko ṣẹyin awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ti wọn fi oogun le kuro kaakiri orilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ kan ti oludari ọrọ to niṣe pẹlu iroyin wọn Maj Gen Michael Onoja fi lede, olu ile-iṣẹ alaabo ni awọn ikọ agbesunmọmi Jama’atu Ahlis Sunna Lidda’awati wal-Jihad ti awọn ọmọ ologun ilẹ wa kọlu ti wọn si tuka ni wọn ṣe ikọlu si ipinlẹ Ọyọ.
Wọn kọ ọrọ to n lọ pe awọn pe awọn agbesunmọmi ti wọn ṣọṣẹ nipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bii ọdaran lasan.
Ile-iṣẹ ajọ alaabo ṣalaye pe ọrọ t’awọn fi lede tẹlẹ ni lati jẹ ki awọn eeyan mọ ohun to n ṣẹlẹ kii ṣe lati fa ibẹru sọkan awọn eeyan.
Wọn wa tẹnpẹlẹ mọ pe awọn ikọ ọmọ ologun ilẹ wa ni ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe eto aabo munadoko lorilẹede Naijira.
Ọrọ yi lo jẹyọ lẹyin ikọlu awọn agbesunmọmi to waye ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ nibi ti wọn ti ji awọn ọmọ ile-iwe ati olukọ gbe ni awọn ile-iwe mẹta ọtọọtọ leyi ti awọn kan si ba iṣẹlẹ laabi naa lọ.