Ẹ Ma Dakẹ O, O N Sunmọ Le Bo Diẹ Diẹ; Opeyemi Aiyeola Ke Pe Awọn L’ọba L’ọba Ati Awọn Amuludun Lori Ọrọ Eto Aabo To N Mẹhe

Gbajugbaja oṣerebinrin Opeyemi Aiyeola ti ke pe awọn ilumọọka, awọn Lade Lade ati awọn ti wọn nifọn lẹẹkanna lawujọ lati ke gbajare lori eto aabo to mẹhe nipinlẹ Ọyọ ati awọn ilu kaakiri ilẹ Yoruba.

O fi ẹbẹ yii lede ninu fọnran kan to fi sori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ. Ninu fọnran naa lo ti rawọ ẹbẹ si awọn ẹni bi ẹni ti wọn si mọ awọn eeyan lawujọ lati fi ohun kun ipe sí ijọba lori awọn ikọlu ati ijinigbe to n gbogun sii nilẹ Yoruba.

O fikun pe ọpọ awọn eeyan lo jẹ pe eto idibo ọdun 2027 to dẹ jẹ pe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nipinlẹ Ọyọ ko ṣe f’ọwọ yẹpẹrẹ mu nitori o ti mu sunmọ ọpọ agbegbe niyẹn.

Aiyeola darukọ ọpọ awọn ilumọọka ati Ori Ade bii Ọọni Ile-Ifẹ, Olubadan, awọn Lade Lade nipinlẹ Eko ati awọn amuludun bii Lege Miami, Eniola Badmus, Laide Bakare, Desmond Elliot, Funke Akindele, ati Toyin Abraham.

O rawọ ẹbẹ si wọn lati fi ipo wọn sọrọ lori ọrọ eto aabo yii ki wọn si kegbajare lori bi awọn araalu ṣe wa nibẹrubojo.

Ọrọ Opeyemi yii jẹyọ lẹyin ikọlu to waye ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ nibi ti awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ti yabo awọn ile-iwe ni agbegbe Ahoro-Esinele ti wọn si ji awọn ọmọ ile-iwe ati awọn olukọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search