Ẹ Sa Fun Jijẹ Ẹran Igbẹ Nitori Ajakalẹ Arun Ebola

Awọn oniṣegun oyinbo lo ti kilọ fawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati yago fun jijẹ ẹran igbẹ latari bi ajakalẹ arun Ebola Virus ṣe ti yọju pada nilẹ adulawọ, to si ṣeeṣe ki eniyan ko arun naa lati ara ẹranko to ba ni.

Awọn onimọ-iṣegun naa ṣalaye pe arun Ebola lo le wọle si ọmọniyan lara latara ẹranko nipasẹ ẹjẹ, omi ara abi ifirakinra pẹlu awọn ẹranko bii ọbọ, adan, inaki ati bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn fi kun pe bi eniyan ba pa eyikeyi ninu wọn, to fọwọ kan wọn abi ṣe wọn lai jina, o ṣeeṣe ki iru ẹni bẹẹ o lu’gbadi arun.

Ikede naa lo n waye tẹle bi arun Ebola ṣe gbode kan pada ni orilẹ-ede D.R Congo ati orilẹ-ede Uganda ti ajọ WHO to n mojuto eto ilera l’agbaye dẹ juwe rẹ gẹgẹ bii arun to n kọ agbaye lominu, ti ko si ti ni abẹrẹ ajẹsara rẹ.

L’ọwọ yii, ajọ WHO ni iye awọn eniyan to ti lu’gbadi arun naa jẹ igba le ni aadọta o din mẹrin (246) ninu eyi ti awọn ọgọrin (80) ninu wọn ti jẹ alaisi ni orilẹ-ede D.R Congo nikan. Ni ti Uganda, eeyan meji pere lo wa ni akọsilẹ ti ọkan ninu wọn si ti jade laye.

Botilẹjẹ pe, orilẹ-ede Naijiria ko ti ni akọle silẹ kankan ṣugbọn ọga agba ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun l’orilẹ-ede Naijiria, Dọkita Jide Idris ni awọn ti wa ni imurasilẹ de arun Ebola bo ba fẹ yọju rara.

Ẹwẹ, akọṣẹmọṣẹ eleto ilera kan lati fasiti Ilorin, Alagba Tanimọla Akande jẹ ko di mimọ pe arun Ebola virus jẹ eyi to ma n wa lara ẹranko, paapaa julọ ẹran igbẹ, ti eniyan si le ko arun naa lasiko ti eniyan ba fẹ ṣ’ọdẹ, ṣe, pa’tẹ abi jẹ ẹran naa, fun idi eyi, o rọ awọn eniyan lati yago fun ẹran igbẹ lasiko yii.

O wa ka awọn apẹrẹ arun Ebola bii, ori-fifọ, iba, irẹwẹsi, ara riro, ọfun didun, sisun ẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lakotan, o rọ awọn eniyan lati yago fun ẹran igbẹ lasiko yii, ki wọn o si la lo ibọwọ lati gba ẹran mu, ki wọn o si ri daju pe ẹran jijẹ n jina de’nu. Bẹẹ ki wọn o dẹ tete ma fi ohun ti wọn ba kẹfin to awọn ijọba ati eleto to yẹ l’eti.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search