Adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NDC, Peter Obi ti jẹjẹ pe Sẹnetọ Rabiu Musa Kwankwanso yoo jẹ igbakeji oun ni ikapa alabaṣiṣẹpọ ti kii ṣe amugba lẹgbẹ lasan ti oun ba wọle gẹgẹ bii aarẹ l’ọdun 2027.
Obi sọ eyi ninu ọrọ rẹ nigba to gba iwe yiyan rẹ gẹgẹ bi adije dupo aarẹ f’ẹgbẹ NDC leyi to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ.
Lana ode yii ni Obi kede Kwankwanso gẹgẹ bii igbakeji rẹ ninu irin-ajo ati jẹ aarẹ l’ọdun 2027. Ti ẹ o ba gbagbe, Obi ati Kwankwanso ni wọn jọ jade dije dupo aarẹ ni idibo to lọ ti wọn si ṣe ipo kẹta ati ikẹrin tẹle ara wọn ti wọn si n bo lẹyin igbakeji aarẹ tẹlẹri Atiku Abubakar to ṣe ipo kẹta ati Aarẹ Tinubu to ṣe ipo kinni.
Obi ṣapejuwe jijade rẹ gẹgẹ bii ipe lati sin ilu to si n jẹjẹ pe orilẹede Naijiria ọtun ti yoo ni iṣọkan, eto aabo gidi, atunṣe si eto ọrọ aje ati iṣejọba to yanranti ni oun maa ṣiṣẹ le lori.