Gbajugbaja onkọrin ẹmi, Yinka Alaseyori l’awọn araalu ti n bẹnu atẹ lu bayii loju opo ayelujara lẹyin to sọ pe adura ni koko lati gba awọn ọmọ ile-iwe ati olukọ ti wọn jigbe n’ipinlẹ Ọyọ.
O sọ eyi ninu fọnran kan to fi lede nibi to ti n gbe aarẹ Tinubu ati awọn ẹṣọ alaabo lẹyin pẹlu bi ọpọ awọn eeyan ṣe n bẹru lori eto aabo to mẹhe.
Gẹgẹ bi Alaṣeyọri ṣe sọ, o ni ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria dẹkun ati jẹ ki awọn kan maa lo wọn fun oṣelu bẹẹ lo n tẹnu mọ pe Aarẹ, igbakeji aarẹ ati awọn ẹṣọ alaabo n ṣiṣẹ takuntakun lati doola awọn ti wọn jigbe.
O tẹsiwaju pe awọn eeyan o le sọ pe ijọba o ṣiṣẹ nitori wọn n gbiyanju agbara wọn. O fikun pe gbogbo wa pata la nilo adura titi kan aarẹ gan.
Alaṣeyọri ni awọn ọmọ ti wọn ko yi jẹ ọmọ fun gbogbo eeyan. O ni o ṣeeṣe ki awọn ẹṣọ alaabo fẹ lo doola awọn ọmọ naa ṣugbọn ki agbara ẹmi okunkun maa da wọn duro leyi to n tọka si pataki adura.
Ọrọ rẹ yii lo ti fa ariyanjiyan lori ẹrọ ayelujara t’awọn kan si n bẹnu atẹ lu pe eto aabo to mẹhe nilo ki ijọba pinnu lati gbe igbesẹ akin lori ẹ kakaki a maa fi kọ ẹsin lọrun.