Lootọ Eto Idibo Abẹle Wa Ni Aiṣedeede – Olori Ẹgbẹ NDC

Olori ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC), Seriake Dickson ti kẹdun pẹlu awọn adije dupo ti wọn kopa ninu eto idibo abẹle to ṣẹṣẹ pari to si n gba pe lootọ ni awọn aiṣedeede wa ninu eto idibo naa.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ loni, Dickson ni bi o tilẹ jẹ pe eto idibo abẹle naa ni abawọn, ki awọn ọmọ ẹgbẹ ni suuru pẹlu ẹgbẹ bi wọn ṣe n gbiyanju lati la awọn ipenija to niṣe pẹlu idagbasoke wọn kọja.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni awọn ipenija ti wọn koju yii ko kii ṣe ẹgbẹ NDC nikan lo kan nitori awọn ẹgbẹ ti wọn nifọn lẹẹkanna gan ni awọn ipenija naa.

O ni oṣu mẹrin pere l’awọn t’awọn si wa laarin asiko perete fun imura idibo leyi ti awọn ti ṣe iforukọsilẹ, apejọpọ, eto idibo abẹle, eto ẹbẹ ati ipari ija bayi.

Ẹni to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa naa di ẹbi awọn aroye to tẹle idibo naa ru ilana a n gba ṣeto idibo abẹle ti o jẹ tipa labẹ ofin eto idibo lorilẹede Naijira.

Pẹlu gbogbo aroye to tẹle idibo naa, agba ẹgbẹ naa ni ẹgbẹ naa ṣe eto idibo ọhun bo ṣe yẹ pẹlu pe ẹgbẹ naa ṣi kere ati aduru awọn adije dupo ti wọn kopa.

Dickson wa ṣe akodanu awọn iroyin l’awọn agbọn kan lori ẹrọ ayelujara pe awọn ti wọn jawe olubori ti han de lati eto idibo naa bẹẹ lo n rọ awọn eeyan lati duro de akọsilẹ ẹgbẹ naa gan gan.

O tẹsiwaju pe awọn ti mọ pe o ṣeeṣe ki ikunsinu wa lẹyin ibo naa nitori rẹ l’awọn ṣe ṣeto ati pari aawọ naa. O wa fi ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ balẹ pe awọn eto idibo abẹle to n bọ o ni ri bẹ.

Ni ipari ọrọ rẹ, Dickson dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin fun iranwọ ati ifọkansi to si ni ẹgbẹ oṣelu NDC jẹ eleyii to n ṣeto iṣuna rẹ fun’ra rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search