jọba ipinlẹ Borno ti ṣe idapada awọn agbesunmọmi okooleleẹdẹgbẹrin (720) ti wọn ti tuba ti wọn si ti pari akanṣe eto atunṣe, irapada ati idapada s’awujọ wọn si inu ilu.
Awọn ipele ti wọn ṣẹṣẹ pari yi ni wọn jẹ ipele kẹsan labẹ akanṣe eto iṣatunṣe ijọba ipinlẹ naa ni wọn bura fun pẹlu Al-Quran ko to di pe wọn da wọn pada si awujọ.
Ẹni to jẹ oludamọran pataki si gomina Babagana Zulum lori eto aabo ọgagun fẹyinti Ishaq Abdullahi sọ eyi nibi ayẹyẹ naa to waye ni Maiduguri lati sami ipari irapada wọn.
O ni eto naa to wa lara awọn igbiyanju ijọba lati f’opin si eto aabo to mẹhe lo bẹrẹ labẹ iṣejọba Zulum ni ọdun 2021 lo ti mu ki ọpọlọpọ awọn agbesunmọmi ti wọn fi tọkantọkan fi ija silẹ.
O tẹsiwaju pe awọn eeyan naa ni wọn kọ ẹkọ Islam ati iṣẹ ọwọ oriṣiriṣi to le wulo fun wọn lawujọ.
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Plateau Caleb Mutfwang ti kede pe oun o ni ba awọn agbesunmọmi duna-dura bẹẹ lo n ṣeleri pe oun maa daabobo awọn araalu ati gbogbo nkan to jẹ ti ijọba nipinlẹ naa. O sọ eyi nibi ajọyọ iṣejọba awaarawa nipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ nipa aabo, Mutfwang ni iṣejọba oun ṣetan lati daabobo ẹmi ati dukiya kaakiri ipinlẹ naa. O ni ki ẹnikẹni ma ro pe igbesunmọmi a fun wọn laaye pẹlu ijọba.
O fikun pe iṣẹ n lọ lọwọ lati gba awọn eeyan sinu ikọ alaabo lati mu ki eto aabo tubọ le dọindọin.