Eyi Nidi Ti Mi O Se Tii L’ọkọ – Mummy Wa

Eyi Nidi Ti Mi O Se Tii L'ọkọ - Mummy Wa

Agbefọnranjade l’ori ayelujara, Kemi Ikuseedun ti gbogbo eeyan mọ si Mummy Wa lo ti ṣalaye idi t’oun o ṣe tii ni ọkọ l’ọmọ ọgbọn ọdun.

Nigba to n sọrọ ninu fọnran kan lo ti ṣalaye pe oun ni iwa ki oun maa ni’fẹ awọn eeyan ninu sinima leyi to n ni ipa lori aye oun.

O ni ọpọlọpọ awọn obinrin ni nkan yii maa n ni ipa lori wọn. O tẹsiwaju pe ni o ku diẹ ki oun pe ọmọ ọgbọn ọdun, oun ṣi n duro de ẹnikan t’oun wo ninu sinima leyi to le ma jẹ pe bẹẹ loni tọun ṣe ri ni oju aye.

O ni lootọ idi t’oun o ṣe tii ni ọkọ ni pe awọn ọkunrin inu sinima l’oun maa n ni’fẹ.

Mummy wa lo ja gbangba pẹlu awọn fọnran apanilẹrin lori ayelujara pẹlu Mr. Macaroni ni ọdun 2020.

Ni bayi, oun ni ẹni akọkọ ti yoo ṣe sinima to ko ti orilẹ-ede Naijiria ati Korea papọ ni ọdun 2024.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search