Ṣeyi Tinubu Fi Ọlọpa Gbe DJ Chicken Ni Lọya Rẹ Ba N Bẹbẹ

Ṣeyi Tinubu Fi Ọlọpa Gbe DJ Chicken Ni Lọya Rẹ Ba N Bẹbẹ

Amofin Rotimi Stephen to jẹ agbẹjọro fun gbajumọ ori ayelujara ti ẹnu kii sin l’ara rẹ iyẹn DJ Chicken lo ma ti n ra’wọ ẹbẹ bayii si gbogbo awọn to ba le ba Ṣeyi Tinubu iyẹn ọmọ Aarẹ Bọla Tinubu s’ọrọ lati f’ọwọ wọ’nu l’ori ọrọ DJ Chicken.

Ninu fọnran kan ti lọya naa ṣe lo ti ni oun kesi gbogbo awọn to ba jẹ ololufẹ DJ Chicken ati awọn to ba le Ba Ṣeyi Tinubu s’ọrọ lati ran wọn l’ọwọ nitori DJ Chicken ti wa ni atimọle bayii ni olu-ile-ise ọlọpa nipinlẹ Eko to wa ni agbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko nitori ọrọ to sọ nipa Ṣeyi Tinubu ati baba rẹ iyẹn aarẹ orilẹ-ede Naijiria ati bi nnkan yoo ṣe ri fun-un ninu idibo to n bọ.

Bi ẹ o ba gbagbe, DJ Chicken lo s’ọrọ ninu fọnran kan l’ori ayelujara pe aarẹ Tinubu ko ni wọ’le saa keji gẹgẹ bii aarẹ, ati pe oun iyẹn DJ Chicken yoo pa Ṣeyi Tinubu danu, ti oju wọn yoo ja.

Ninu ọrọ lọya DJ Chicken, o ni afi ki wọn bẹ Ṣeyi Tinubu ko gbọ nitori gbogbo ẹri lo ti fi han lootọ pe ni onibara rẹ iyẹn DJ Chicken jẹbi, ẹbẹ lasan lo ku lati bẹ, ati pe DJ Chicken naa ti ṣalaye pe oun ko ka ọrọ naa si rara, to kan jẹ ọrọ asọjẹ l’asan.

Amofin Rotimi Stephen o ṣai m’ẹnuba ba pe ara onibara rẹ ko fi bẹẹ da, ti ọpọlọ a si maa tase, koda eyi gan-an kun ara idi ti oun fi n duro tii gẹgẹ bii ara ọna ti oun fi n ran awujọ l’ọwọ gẹgẹ bii agbẹjọro.

Ni kukuru, lọya DJ Chicken ni awọn ki aye dakun rawọ ẹbẹ si Ṣeyi Tinubu l’ori bi DJ Chicken ṣe ti lọ f’ẹnu ja waya s’awọn alagbara.

O ni gbogbo awọn nnkan wọn yii lo ran oun l’ọwọ l’onii lati jẹ akinkanju, alakitiyan ati ẹni to ko ara rẹ ni ijanu.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search